“Àwọn Obìnrin Láyè Tiwọn Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìkọ́lé”
Iléeṣẹ́ kan táwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé bọ̀wọ̀ fún lórílẹ̀-èdè Britain ti gbóríyìn fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí bí wọ́n ṣe dá àwọn obìnrin lẹ́kọ̀ọ́ láti máa wa àwọn maṣíìnì ńláńlá níbi tí wọ́n ń kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn tuntun sí nítòsí Chelmsford nílùú Essex. Àjọ Considerate Constructors Scheme * (CCS) sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbégbá orókè pẹ̀lú bí wọ́n ṣe dá àwọn obìnrin lẹ́kọ̀ọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé, wọ́n sì kí wọn kú làákàyè. Kí nìdí tí àjọ yìí fi sọ pé wọ́n gbégbá orókè?
Lórílẹ̀-èdè Britain, tá a bá kó ogọ́rùn-ún [100] èèyàn tó ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé jọ, àwọn tó jẹ́ obìnrin nínú wọn ò pé mẹ́tàlá [13]. Nínú ìwádìí tí iléeṣẹ́ kan ṣe ní Britain ṣe, àwọn ọ̀dọ́bìnrin tó máa ń fẹ́ ṣiṣẹ́ ìkọ́lé ò tó nǹkan. Àmọ́ èyí yàtọ̀ pátápátá sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ níbi iṣẹ́ ìkọ́lé táwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe ní Chelmsford. Àwọn obìnrin tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀. Àmọ́ tá a bá ní ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ń fi ẹ̀rọ ńlá ṣiṣẹ́, obìnrin ló pọ̀ jù nínú wọn.
Kí ló ń ran àwọn obìnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ wọn láṣeyọrí? Ipa kékeré kọ́ ni ìdálẹ́kọ̀ọ́ àti ìtìlẹ́yìn tí wọ́n ń rí gbà ń kó. Ohun méjì yìí náà sì wà lára ohun tí àjọ CCS ń tẹ̀ lé tó bá dọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìkọ́lé. Àjọ náà rọ àwọn òṣìṣẹ́ ìkọ́lé pé kí wọ́n fi hàn pé àwọn mọyì àwọn tó ń bá wọn ṣiṣẹ́ nípa pé kí wọ́n “rí sí i pé wọ́n fọ̀wọ̀ wọ kálukú níbi iṣẹ́, kí wọ́n má ṣe ojúsàájú, kí wọ́n máa gbé wọn ró, kí wọ́n sì má tì wọ́n lẹ́yìn,” àti pé “kí wọ́n máa dá wọn lẹ́kọ̀ọ́.”
Wọ́n Ń Dá Àwọn Obìnrin Lẹ́kọ̀ọ́ Lórí Bí Wọ́n Á Ṣe Máa Lo Àwọn Maṣíìnì Ńláńlá
Jade, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn obìnrin tí wọ́n dá lẹ́kọ̀ọ́ lórí bí wọ́n ṣe ń wa katakata àtàwọn ọkọ̀ ńlá tí wọ́n fi ń kó yẹ̀pẹ̀, sọ pé: “Ó yà mí lẹ́nu gan-an! Mi ò rò ó rí pé mo lè ṣe é. Ìgbà míì wà tíṣẹ́ yẹn máa ń le, àmọ́ léraléra ni wọ́n ń dá mi lẹ́kọ̀ọ́, tí mo sì ń kọ́ nǹkan tuntun.” Bíi ti Jade, Lucy náà ti ń wa àwọn maṣíìnì ńláńlá yẹn. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ níbi ìkọ́lé náà, kò sí iṣẹ́ ọwọ́ kan pàtó tí mo lè sọ pé mo mọ̀ ọ́n ṣe. Àmọ́ lọ́jọ́ àkọ́kọ́ tí mo débẹ̀ báyìí ni wọ́n ti dá mi lẹ́kọ̀ọ́. Látìgbà yẹn, àwùjọ márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni mo ti bá ṣiṣẹ́, ìyẹn ti jẹ́ kí n gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ gan-an!”
Iṣẹ́ táwọn obìnrin yìí mọ̀ ọ́n ṣe kọjá kí wọ́n kàn lo àwọn maṣíìnì yẹn nìkan. Eric, tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tó ń darí àwọn tó ń ṣiṣẹ́ kíyè sí i pé: “Àwọn obìnrin mọ àwọn maṣíìnì yẹn tọ́jú ju àwọn ọkùnrin lọ, àwọn ni wọ́n sì máa ń kọ́kọ́ mọ̀ tí nǹkan bá ti ń ṣe maṣíìnì wọn, tí wọ́n á sì lọ sọ fáwọn tó máa bójú tó o.”
Wọ́n Ń Ti Àwọn Obìnrin Lẹ́yìn Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìkọ́lé
Carl, tó ń darí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń fi maṣíìnì ṣiṣẹ́ sọ pé: “Báwọn obìnrin ṣe kọ́ bí wọ́n á ṣe máa wa maṣíìnì ńláńlá wú mi lórí gan-an. Kódà nígbà míì, ó tẹ́ mi lọ́rùn kí àwọn wà á dípò kí n sọ pé káwọn ọkùnrin tó ti ń lò ó fọ́pọ̀ ọdún wà á!”
Tí àwọn tó ń darí àwọn èèyàn ṣíṣẹ́ bá fi han àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ pé àwọn wà lẹ́yìn wọn, ó máa ń fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Therese nìyẹn. Ó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ lílo maṣíìnì láti ṣiṣẹ́, ó sì mọ̀ pé tó bá dọ̀rọ̀ ká wa àwọn maṣíìnì ńláńlá yìí, ó ṣe pàtàkì gan-an kéèyàn gbaṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́, kó sì ṣàwọn ìpinnu tó máa fi hàn pé kò fọ̀rọ̀ ààbò ṣeré. Therese ṣàlàyé pé: “Tí mo bá ti mọ̀ pé gbágbáágbá ni ẹni tó ń darí wa ṣíṣẹ́ wà lẹ́yìn mi, ó máa ń jẹ́ kí n ṣiṣẹ́ ju bí mo ṣe rò lọ torí ṣe lọkàn mi máa ń balẹ̀ pé wọ́n fọkàn tán mi. Kò sí bí mi ò ṣe lè ṣiṣẹ́ kára tó, tí mo bá ti mọ̀ pé àwọn èèyàn mọrírì iṣẹ́ tí mò ń ṣe, tí wọn ò sì fọwọ́ rọ́ ọ tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan!”
Abigail, tóun náà ń wa katakata àtàwọn ọkọ̀ ńlá tí wọ́n fi ń kó yẹ̀pẹ̀, mọrírì bí wọ́n ṣe ń tì í lẹ́yìn, tí wọ́n sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀, ó ní: “Àwọn ọkùnrin tá a jọ ń ṣiṣẹ́ níbí kì í fojú kéré mi. Wọ́n ṣe tán láti ràn mí lọ́wọ́, àmọ́ wọn kì í gbaṣẹ́ mi ṣe. Tí wọ́n bá ti ràn mí lọ́wọ́ tán, wọ́n á jẹ́ kí n máa báṣẹ́ lọ.”
Àwọn Òṣìṣẹ́ Tó Ń Pọkàn Pọ̀, Tí Wọ́n sì Lẹ́rìí Ọkàn
Yàtọ̀ sí pé àwọn obìnrin tó wà ní Chelmsford ń fi oríṣiríṣi maṣíìnì ṣiṣẹ́, wọ́n tún dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ lórí bí wọ́n ṣe lè wọn ilẹ̀, bí wọ́n ṣe lè ṣọ́ ilẹ̀ lò, bí wọ́n ṣe ń tún maṣíìnì ṣe àti bí wọ́n ṣe ń de irin táwọn òṣìṣẹ́ á máa dúró lé ṣiṣẹ́. Robert, tó ti bá àwọn obìnrin ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́, sọ pé wọ́n máa ń “pọkàn pọ̀, ó máa ń yá wọn lára láti ṣiṣẹ́, wọ́n sì máa ń lákìíyèsí dórí bíńtín.” Tom, tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń wọnlẹ̀, fi kún un pé: “Afínjú làwọn obìnrin tá a jọ ń ṣiṣẹ́, wọ́n sì lẹ́rìí ọkàn. Wọ́n máa ń fẹ́ ṣe nǹkan lọ́nà tó ṣe rẹ́gí.”
Abájọ tí Fergus tó wà lára àwọn òṣìṣẹ́ ṣe fọ̀yàyà sọ pé: “Ó dájú pé àwọn obìnrin láyè tiwọn lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé!”
^ ìpínrọ̀ 2 Àjọ Considerate Constructors Scheme kì í ṣe tìjọba, aládàáni ni. Iṣẹ́ wọn ni láti máa mú kí iṣẹ́ ìkọ́lé sunwọ̀n sí i ní Britain.