Fọ́tò Oríléeṣẹ́ Wa Tuntun ní Warwick, Apá 7 (September 2016 sí February 2017)
Wo ọ̀wọ́ àwọn fọ́tò yìí kó o lè rí bá a ṣe parí iṣẹ́ lórí oríléeṣẹ́ tuntun tó jẹ́ ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àti bí àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í lo àwọn ilé yìí láti September 2016 sí February 2017.
September 8, 2016—Ọgbà Warwick
Wọ́n ti ń lo gbogbo ilé tó wà ní oríléeṣẹ́ náà báyìí. Níbẹ̀rẹ̀ oṣù September, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún [500] èèyàn ló ń gbé níbẹ̀. Lára wọn ni àwọn òṣìṣẹ́ ìkọ́lé tó yọ̀ǹda ara wọn àtàwọn òṣìṣẹ́ alákòókò kíkún tí wọ́n kó wá láti ọ́fíìsì tó wà ní Brooklyn tẹ́lẹ̀.
September 20, 2016—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́
Ayàwòrán kan ń wo àwọn àwo tí wọ́n lẹ̀ mọ́ ara ògiri ibi àbáwọlé síbi tí wọ́n gbé àtẹ tá a pè ní “A People for Jehovah’s Name” sí. Wọ́n ṣe àwọn àwo náà lọ́nà tó fi máa rí bíi ti ìṣẹ̀ǹbáyé, èyí sì bá a mu gan-an torí pé ìtàn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá ni ìpàtẹ náà dá lé.
September 28, 2016—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́
Stephen Lett, tó wà lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló darí Ìjọsìn Òwúrọ̀ àkọ́kọ́ tó wáyé ní Warwick, tá a gbé sáfẹ́fẹ́. Láàárọ̀ ọjọ́ yẹn, Arákùnrin Lett ka lẹ́tà kan láti dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27,000] tó yọ̀ǹda ara wọn láti kọ́ oríléeṣẹ́ tuntun náà àti ọ̀pọ̀ àwọn míì tó kọ́wọ́ ti iṣẹ́ náà lọ́nà kan tàbí òmíì.
October 3, 2016—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́
Oníṣẹ́ ọnà kan ń to àwọn álífábẹ́ẹ̀tì sára àwòrán tí wọ́n máa gbé sẹ́nu ọ̀nà ọ̀kan lára àwọn ìpàtẹ mẹ́ta táwọn èèyàn máa wò fúnra wọn. Àtẹ tá a pè ní “A People for Jehovah’s Name” yìí sọ ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti ọdún 1870 títí di àkókò yìí.
October 5, 2016—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́
Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé àtàwọn olùrànlọ́wọ́ wọn pẹ̀lú àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Ìkọ̀wé jọ ń ṣèpàdé. Àwọn àwòrán tí wọ́n ń gbé yẹ̀ wò bóyá wọ́n máa lò nínú ìwé tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ jáde ló wà lójú tẹlifíṣọ̀n kan, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ láwọn ẹ̀ka míì níbòmíì tí wọ́n jọ ń ṣèpàdé yìí ló sì wà lójú tẹlifíṣọ̀n kejì. Brooklyn ni wọ́n ti gbé tábìlì yìí wá sí Warwick. Ẹnì kan ló fi ṣètọrẹ fún ètò wa lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn.
October 20, 2016—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́
Ọ̀kan lára àwọn olùrànlọ́wọ́ Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí àtàwọn arákùnrin tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ ń ṣèpàdé lórí bí wọ́n ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn tí ìjì líle Super Typhoon Haima (tí wọ́n tún ń pè ní Lawin) tó jà lọ́jọ́ tó ṣáájú ọjọ́ yẹn ní Philippines ṣèpalára fún. Àwọn kọ̀ǹpútà ìgbàlódé máa ń jẹ́ kó rọrùn fáwọn ẹ̀ka tó wà ní oríléeṣẹ́ láti tètè bójú tọ́ ọ̀rọ̀ pàjáwìrì, ó sì máa ń jẹ́ kó rọrùn fún wọn láti kàn sí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì káàkiri ayé.
October 28, 2016—Ọ́fíìsì Àwọn Tó Ń Ṣe Àtúnṣe Ilé àti Ibi Ìgbọ́kọ̀sí
Adágún kékeré yìí wà láàárín Ọ́fíìsì Àwọn Tó Ń Ṣe Àtúnṣe Ilé àti títì ńlá tó wọnú ọgbà. Adágún yìí àtàwọn omi adágún míì tó wà ní Warwick máa ń fi ewéko àtàwọn ohun míì tí Ọlọ́run dá sínú omi sẹ́ omi òjò tó bá rọ̀ sínú rẹ̀, ìyẹn sì ń bá wa ṣọ́wó ná, torí pé ìdajì owó tá ò bá ná ká ní a fẹ́ ṣe ohun tí wọ́n máa ń ṣe sí ọ̀pọ̀ ilé là ń ná báyìí. Yàtọ̀ síyẹn, kí omi òjò tó ṣàn kúrò níbi adágún náà lọ sínú àwọn odò míì tó wà láyìíká, ó ti máa mọ́ torí adágún náà á ti sẹ́ ẹ, kò sì ní ṣèpalára fáwọn ewéko àtàwọn ẹranko.
November 4, 2016—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́
Àwọn òṣìṣẹ́ yìí ń kó ẹrù jáde níbi tí wọ́n já a sí. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rin [80] òṣìṣẹ́ tó ran àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní oríléeṣẹ́ lọ́wọ́ láti kó ẹrù wọn kúrò ní Brooklyn lọ sí ilé wọn tuntun ní Warwick.
December 14, 2016—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́
Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nílé ìdáná da ìyẹ̀fun tí wọ́n ti pò látinú pọ́ọ̀tù ńlá kan sórí tábìlì. Ẹ̀rọ tó ní pọ́ọ̀tù ńlá yìí máa jẹ́ kíṣẹ́ náà rọrùn fún wọn, kò sì ní pa wọ́n lára torí pé ìyẹ̀fun tí wọ́n pò náà pọ̀, ó tiẹ̀ máa ń wúwo ju kìlógíráàmù márùndínláàádọ́ta [45] lọ nígbà míì. Níbi tí wọ́n ti ń ṣe búrẹ́dì nílé ìdáná náà, wọ́n ní ẹ̀rọ kan tí wọ́n máa ń gbé ìyẹ̀fun tí wọ́n bá pò sí. Ẹ̀rọ yìí máa ń gbóná, ó sì máa ń tutù fúnra rẹ̀; èyí máa ń jẹ́ kí búrẹ́dì wú bí wọ́n bá ṣe fẹ́ kó tètè wú tó. Ẹ̀rọ yìí ń dín iṣẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ kù gan-an, torí pé kì í ṣe iṣẹ́ kékeré láti máa ṣe ọgọ́rọ̀ọ̀rún búrẹ́dì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.
December 14, 2016—Ọ́fíìsì Àwọn Tó Ń Ṣe Àtúnṣe Ilé àti Ibi Ìgbọ́kọ̀sí
Àwọn òṣìṣẹ́ tó ń tọ́jú ilé ń gbé ìdọ̀tí jáde nínú Ọ́fíìsì Àwọn Tó Ń Ṣe Àtúnṣe Ilé. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ilé wa ní Warwick ló já síra wọn, kò dà bíi ti Brooklyn. Èyí bá wa dín àwọn òṣìṣẹ́ àti mọ́tò táá máa nílò kù, táá máa kó ìdọ̀tí àtàwọn ohun tó ṣeé tún lò jáde.
December 14, 2016—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́
Wọ́n ń fi omi wọ́n aṣọ kan kí àwọn ibi tó rún lára rẹ̀ lè rọ̀, kí wọ́n tó wá lọ̀ ọ́. Tá a bá pín in dọ́gba lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Aṣọ Fífọ̀ ní Warwick máa ń fọ aṣọ tí àròpọ̀ wọn wúwo ju ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] kìlógíráàmù lọ. Kí aṣọ àwọn èèyàn má bàa dà pọ̀, ṣe làwọn òṣìṣẹ́ máa ń lẹ nǹkan pélébé kan tó ní nọ́ńbà mọ́ aṣọ kọ̀ọ̀kan. Wọ́n á wá máa fi ẹ̀rọ kan yẹ̀ ẹ́ wò ní gbogbo ibi tí aṣọ náà bá dé nínú ilé ìfọṣọ kí wọ́n má bàa ṣi aṣọ kó fún aláṣọ, kó lè jẹ́ pé gbogbo aṣọ tó bá ní nọ́ńbà kan náà ni wọ́n á kó lọ sí ọ́fíìsì tàbí yàrá tó yẹ.
December 20, 2016—Ọ́fíìsì Àwọn Tó Ń Ṣe Àtúnṣe Ilé àti Ibi Ìgbọ́kọ̀sí
Onímọ̀ ẹ̀rọ kan ń ṣàyẹ̀wò ẹ̀rọ kan tí wọ́n fi ń gbé nǹkan ròkè nínú ilé ibi tí àwọn jẹnẹrétọ̀ wà. Àyẹ̀wò tó ń ṣe yìí máa jẹ́ kí ẹ̀rọ náà lálòpẹ́, kò sì ní jẹ́ kó pa àwọn tó bá ń lò ó lára.
January 10, 2017—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́ẹ́
Onímọ̀ ẹ̀rọ kan ń fi kọ̀ǹpútà ṣiṣẹ́ lórí àwọn àwòrán tó ṣàlàyé ohun tí ìpàtẹ tá a pè ní “Faith in Action” dá lé.
January 11, 2017—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́
Àwọn òṣìṣẹ́ ń ṣètò kẹ̀kẹ́ yìí kí wọ́n lè gbé e síbi ìpàtẹ tá a pè ní “A People for Jehovah’s Name.” Ọdún 1903 ni wọ́n ṣe kẹ̀kẹ́ yìí, ẹnì kan ló sì fún wa. Àwọn òṣìṣẹ́ ní Warwick fẹ́ fara balẹ̀ gbé e síbi ìpàtẹ yìí, kí àwọn tó bá wá wò ó lè rí iṣẹ́ àṣekára táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì (tá à ń pè ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí) ti ṣe sẹ́yìn àti bí wọ́n ṣe fẹ̀mí ara wọn wewu láti máa fi irú kẹ̀kẹ́ yìí rìnrìn àjò káàkiri bí wọ́n ṣe ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
January 12, 2017—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́
Àwọn káfíńtà ń de gíláàsì kan mọ́ ibi tí àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé tó jẹ mọ́ àwòkẹ́kọ̀ọ́ “Photo-Drama of Creation” máa wà. Àwòkẹ́kọ̀ọ́ tó dá lórí Bíbélì ni, ó ní fọ́tò lóríṣiríṣi, òun sì ni àkọ́kọ́ irú ẹ̀ tó máa jáde. Ọdún 1914 ni wọ́n gbé e jáde, àwọn tó sì wò ó lọ́dún yẹn fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́sàn-án.
January 12, 2017—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́
Àwọn méjì tó ń tọ́jú àwọn nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé àti ẹnì kan tó máa ń fi kọ̀ǹpútà to àwòrán jọ ń ṣètò Bíbélì Zurich Latin Bible tí wọ́n ṣe lọ́dún 1544 kí wọ́n lè fi kún àwọn Bíbélì tó wà níbi àtẹ “The Bible and the Divine Name.” Àmì pupa tó wà nínú Bíbélì tí wọ́n ṣí sílẹ̀ lápá òsì yìí ń tọ́ka sí ibi tí Jèhófà tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run wà. Àwọn tó ń tọ́jú àwọn nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé máa ń ṣe oríṣiríṣi nǹkan sí àwọn Bíbélì tó ti pẹ́ yìí torí ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ti gbó. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń fi àwọn ike pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ sí eteetí àwọn ojú ìwé náà kó lè nà dáadáa. Bákan náà, wọ́n máa ń rí i pé ibi tí wọ́n pàtẹ àwọn Bíbélì náà sí ò móoru jù, kò sì tutù jù, wọ́n sì máa ń rí i pé iná tó ń tàn níbẹ̀ ò le débi tó máa ba bébà tí kò lágbára tí wọ́n fi ṣe àwọn Bíbélì náà jẹ́.
January 16, 2017—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́
Kí àwọn àlejò lè rí ọgbà Warwick dáadáa látòkè, àwọn tó ń mú wọn yí ká mú wọn lọ sí òkè ilé gogoro tó wà níbẹ̀, tó ga tó ẹsẹ̀ bàtà márùndínlọ́gọ́rin [75]. April 3, 2017 làwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í forúkọ sílẹ̀ pé àwọn fẹ́ wá wo ọgbà oríléeṣẹ́ wa àtàwọn ìpàtẹ tó wà níbẹ̀. Àwọn tó bá fẹ́ wá wo oríléeṣẹ́ wa gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ forúkọ sílẹ̀ látorí ìkànnì ká lè mọ ìgbà tí wọ́n máa wá. Tẹ́ ẹ bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ lọ sórí ìkànnì wa, kẹ́ ẹ lọ sí NÍPA WA > Ọ́FÍÌSÌ ÀTI RÍRÌN YÍ KÁ ỌGBÀ.
January 19, 2017—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́
Ẹni yìí wà lára àwọn tó ń tọ́jú àwọn nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé. Bíbélì King James Version tí wọ́n ṣe lọ́dún 1611, èyí tó ṣọ̀wọ́n gan-an, ló gbé dání yẹn. Ó ń gbé e sínú àwo fífẹ̀ kan tó nípọn, tó máa gbà á dúró, táá jẹ́ kó lè wà ní ṣíṣí tí àwọn àlejò bá wá wo ìpàtẹ náà. Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní oríléeṣẹ́ wa ló ṣe àwọn àwo tó nípọn yìí.
January 19, 2017—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́
Oníṣẹ́ ọnà kan ń fi fìlà sínú àpótí onígíláàsì kan tí wọ́n pàtẹ àwọn nǹkan kan sí. Joseph F. Rutherford ló ni fìlà yẹn, arákùnrin yẹn ló mú ipò iwájú nínú ètò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ọgọ́rùn-ún [100] ọdún sẹ́yìn. Àwọn ohun tó wà nínú àpótí yìí wà lára ìpàtẹ “A People for Jehovah’s Name,” ó jẹ́ ká rí báwọn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyé ìgbà yẹn ṣe sapá láti wàásù ìhìnrere Ìjọba Ọlọ́run.
January 20, 2017—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́
Wọ́n ń gbohùn ẹnì kan sílẹ̀. Ẹni yìí ló ka ìtàn tó bá ìpàtẹ “The Bible and the Divine Name” rìn sórí ẹ̀rọ. Kò ju ọ̀sẹ̀ kan àti ọjọ́ mélòó kan tí wọ́n tú yàrá ìgbohùnsílẹ̀ náà àtàwọn irinṣẹ́ míì tí wọ́n ń lò ní Brooklyn palẹ̀, tí wọ́n sì kó wọn wá sí Warwick tí wọ́n fi tún un tò, tí wọ́n sì pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í gbohùn sílẹ̀. Wọ́n máa ń lo yàrá ìgbohùnsílẹ̀ tó wà ní Warwick yìí náà láti gbohùn àwọn tó ka Bíbélì Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì sílẹ̀, títí kan Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, àwọn àpilẹ̀kọ orí ìkànnì jw.org àtàwọn ìtẹ̀jáde míì tá a kà sórí ẹ̀rọ (bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower tó wà ní Patterson ni yàrá ìgbohùnsílẹ̀ tá a ti ń ṣe èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn iṣẹ́ yìí wà).
January 27, 2017—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́
Ẹnì kan ń fi ọ̀dà kun eteetí ibì kan tí wọ́n lẹ oríṣiríṣi fọ́tò mọ́. Àwọn fọ́tò náà wà lára ìpàtẹ tá a pè ní “A People for Jehovah’s Name.” Fọ́tò àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó gbé láyé ní apá ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún ni.
February 15, 2017—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́
Ayàwòrán kan ń kun ère Kọ́lá tó wà nínú fídíò bèbí tá à ń pè ní Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà. Wọ́n máa gbé e sí apá ibi tí wọ́n ti máa ṣàlàyé àwọn ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe, ní pàtàkì fáwọn ọmọdé.
February 15, 2017—Àwọn Ọ́fíìsì àti Ilé Tó Wà fún Onírúurú Iṣẹ́
Òṣìṣẹ́ kan ń gé fọ́tò àtàwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa lẹ̀ mọ́ ibi ìpàtẹ “A People for Jehovah’s Name.” Ó lé ní igba àti àádọ́ta [250] èèyàn, títí kan àwọn káfíńtà, àwọn onímọ̀ kọ̀ǹpútà, àwọn tó ń ṣe nǹkan lọ́ṣọ̀ọ́, àwọn oníṣẹ́ iná, àwọn tó ń lẹ àwo mọ́ ara ilé, àwọn tó ń fi fídíò yàwòrán àtàwọn tó ń kọ̀wé, tí wọ́n ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìpàtẹ mẹ́ta náà látìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí.