Orin Ìyìn sí Ọlọ́run Lónírúurú Èdè
Kò rọrùn láti tú orin láti èdè kan sí èdè míì. Iṣẹ́ ńlá gbáà ni láti túmọ̀ orin márùnléláàádóje [135] tó wà nínú ìwé orin wa.
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sapá láti ṣe iṣẹ́ bàǹtà banta yìí, láàárín ọdún mẹ́ta, a ti túmọ̀ gbogbo orin tuntun inú ìwé Kọrin sí Jèhófà sí èdè mẹ́rìndínlọ́gọ́fà [116]. A ti ṣe ẹ̀dà ìwé orin tó ní orín márùndínlọ́gọ́ta [55] ní èdè márùndínlọ́gọ́ta [55] míì. Iṣẹ́ ṣì ń lọ ní pẹrẹu láti mú ẹ̀dà ìwé orin yìí jáde láwọn èdè míì.
Bá A Ṣe Ń Túmọ̀ Orin àti Bá A Ṣe Ń Kọ Àwọn Ọ̀rọ̀ Rẹ̀
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń túmọ̀ àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600] èdè, nǹkan bí ọgọ́rùn mẹ́rin [400] àwọn ìwé yìí sì ti wà lórí ìkànnì. Àmọ́ iṣẹ́ ìtumọ̀ orin kò rọrùn bí àwọn iṣẹ́ ìtumọ̀ míì. Kí nìdí? Ìdí ni pé ohùn orin inú Kọrin sí Jèhófà kò yàtọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èdè la ti tú àwọn ọ̀rọ̀ orin náà sí.
Bí a ṣe máa ń tú àwọn ọ̀rọ̀ orin yàtọ̀ sí bí a ṣe máa ń tú àwọn ìwé ìròyìn. Bí àpẹẹrẹ, tí àwọn atúmọ̀ èdè bá ń tú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sí èdè míì, wọ́n máa ń rí i dájú pé wọ́n gbé ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ èdè tí wọ́n ń tú yọ lọ́nà tó péye ní èdè àbínibí tí wọ́n ń tú u sí. Ọ̀rọ̀ orin títú yàtọ̀ pátápátá.
Bí Wọ́n Ṣe Ń Ṣe É
Ọ̀nà tó yàtọ̀ díẹ̀ làwọn atúmọ̀ èdè tó ń túmọ̀ orin máa ń gbà ṣe é torí pé ọ̀rọ̀ orin tí wọ́n ń tú gbọ́dọ̀ nítumọ̀, kó dùn-ún gbọ́ létí, kó sì rọrùn láti rántí.
Ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa lò nínú orin ìyìn gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí táwọn tó ń kọrin á lóye ìtumọ̀ rẹ̀, tí wọ́n á sì tètè mọ ìdí tá a fi lo ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀rọ̀ tó wà nínú orin náà. Ní gbogbo èdè, ó yẹ kí àwọn ọ̀rọ̀ orin àti ohùn orin bára mu, kó sì dùn lẹ́nu ẹni tó ń kọrin bíi pé ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ ló ń kọ lórin.
Báwo làwọn atúmọ̀ èdè ṣe máa ń rí àwọn ohun tá a sọ yìí ṣe? Dípò kí wọ́n máa tú ọ̀rọ̀ orin tó wà nínú Kọrin sí Jèhófà lédè Gẹ̀ẹ́sì ní tààràtà, ìtúmọ̀ tàbí àwọn kókó inú ọ̀rọ̀ orin náà ni wọ́n sọ pé kí àwọn atúmọ̀ èdè máa tú. Bí wọ́n ṣe ń sapá láti rí i pé ọ̀rọ̀ orin kọ̀ọ̀kan bá àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a gbé e kà mu, wọ́n máa ń gbìyànjú láti lo àwọn ọ̀rọ̀ tá a máa ń lò dáadáa, táá rọrùn lóye, téèyàn á sì máa rántí.
Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ni pé wọ́n á kọ́kọ́ tú orin náà bó ṣe wà gẹ́lẹ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì. Lẹ́yìn náà, Ẹlẹ́rìí kan tó mọ̀ nípa orin dáadáa á wá tún àwọn ọ̀rọ̀ inú orin yẹn ṣe kó lè dùn-ún kọ gan-an, kó sì nítumọ̀ lédè tí wọ́n tú orin náà sí. Àwọn atúmọ̀ èdè àtàwọn tó máa ń kà ohun tí wọ́n bá tú láti ṣàtúnṣe tó bá yẹ sí i máa ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ orin náà kí wọ́n lè rí i dájú pé ó bá Bíbélì mu.
Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé dùn gan-an láti gba ìwé orin tuntun náà, àwọn míì sì ń retí pé kó jáde lédè wọn.