Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌKÀNNÌ JW.ORG

Bó O Ṣe Lè Lo Ẹ̀dà Bíbélì Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́

Bó O Ṣe Lè Lo Ẹ̀dà Bíbélì Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́

Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun (èdà tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì) ní oríṣiríṣi ohun tó o lè fi kẹ́kọ̀ọ́ kó o sì gbádùn ẹ̀, bíi:

  • Àlàyé tó nasẹ̀ ohun tó wà nínú ìwé Bíbélì kan, tó fi mọ́ fídíò tó nasẹ̀ ìwé Bíbélì náà

  • Àlàyé ṣókí tàbí àkópọ̀ ohun tó wà nínú ìwé Bíbélì kan

  • Àlàyé ìkẹ́kọ̀ọ́ lórí ẹsẹ kan

  • Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé lórí àwọn ọ̀rọ̀ kan

  • Atọ́ka tá a tò lẹ́sẹẹsẹ

  • Àwòrán àti fídíò

  • Àwọn àfikún tó ní àwòrán ilẹ̀, àtẹ àtàwọn ìwádìí míì

  • Àtẹ́tísí orí kọ̀ọ̀kan

  • Àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì míì

October 2015 la mú ẹ̀dà tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Mátíù jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì. Àá máa fi àwọn ìwé yòókù kún un tá a bá ti parí iṣẹ́ lórí wọn.

Lo àwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí kó o lè mọ bá a ṣe ń lo Bíbélì Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́:

 Lọ sí Ìwé Bíbélì Kan àti Orí Ìwé Kan

Lọ sí PUBLICATIONS > BIBLE kó o wá tẹ àwòrán ẹ̀yìn ìwé New World Translation of the Holy Scriptures (study edition) tàbí ìlujá tó wà nísàlẹ̀ rẹ̀.

  • Ní abala Table of Contents, wàá rí gbogbo ìwé Bíbélì tó wà, ó máa kùn ún ní àwọ̀ búlúù.

  • Wàá tún rí ìlujá àwọn ìsọfúnni míì, bí àlàyé ọ̀rọ̀, àfikún lóríṣiríṣi, àwòrán àti fídíò.

  • Tẹ bọ́tìnì tó ní àmì tó-tò-tó mẹ́rin kó lè to àwọn ohun tó wà nínú Bíbélì náà sẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn. Èyí tí kọ̀ǹpútà máa ń yàn nìyí, àfi tó o bá yí i pa dà.

  • Tẹ bọ́tìnì tó ní igi gbọọrọ mẹ́ta kó lè to àwọn ohun tó wà nínú Bíbélì náà ní gbọọrọ, á to àwọn ìwé inú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, á sì tó àwọn ìwé inú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kejì.

Tẹ ìwé Bíbélì kan. Wàá rí àwọn orí tó wà níbẹ̀, àlàyé ṣókí nípa ìwé náà àti bọ́tìnì méjì míì:

  • Àkọ́kọ́, àlàyé tó nasẹ̀ ìwé Bíbélì náà, àti fídíò.

  • Ìkejì, àlàyé ṣókí nípa ìwé Bíbélì náà.

  • Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun máa ń ṣe àlàyé ṣókí nípa orí kọ̀ọ̀kan nínú ìwé Bíbélì, àmọ́ àlàyé ṣókí ti Bíbélì Ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí máa ń jẹ́ àwọn ohun tí ìwé Bíbélì kọ̀ọ̀kan dá lé.

Yan orí tó o fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́.

Àpótí méjì tó wà lókè máa jẹ́ kó o rí ìwé tó o ṣí lọ́wọ́lọ́wọ́ àti orí tó ò ń kà. O lè yan ìwé Bíbélì míì tàbí orí míì níbẹ̀, tàbí kó o yan ohun míì tó o lè fi kẹ́kọ̀ọ́, bí àlàyé ṣókí nípa ìwé náà tàbí àlàyé ọ̀rọ̀.

Lo Àwọn Ohun Èlò Ìkẹ́kọ̀ọ́ fún Orí Ìwé Kan

Wàá rí àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú orí ìwé Bíbélì tó o ṣí ní Abala Ìkàwé ọwọ́ òsì lójú fóònù ẹ, wàá sì rí Abala Ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ ọ̀tún. (Àkíyèsí: Lórí àwọn fóònù tí ojú rẹ̀ ò fẹ̀, ó máa kọ́kọ́ fi Abala Ìkẹ́kọ̀ọ́ náà pa mọ́, àmọ́ tó o bá tẹ nọ́ńbà tó wà níwájú ẹsẹ kan tàbí tó o tẹ àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, atọ́ka tàbí bọ́tìnì |<uF0DF>, ó máa gbé e wá.)

 Wo àlàyé ṣókí nípa bó o ṣe lè lo àwọn ohun èlò ìkẹ́kọ̀ọ́:

  • Tẹ nọ́ńbà tó wà níwájú ẹsẹ kan tàbí orí kan kó o lè rí àwọn ohun tó wà lórí ẹsẹ yẹn ní Abala Ìkẹ́kọ̀ọ́.

  • Tẹ àmì àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé kó o lè rí àlàyé ìsàlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ kan.

  • Tẹ álífábẹ́ẹ̀tì tá a fi ṣe atọ́ka kó o lè rí atọ́ka náà ní Abala Ìkẹ́kọ̀ọ́, kó o sì rí ẹsẹ Bíbélì tá a tọ́ka sí.

  • Tó o bá fẹ́ gbọ́ àtẹ́tísí orí tó ò ń kà, bẹ̀rẹ̀ láti ẹsẹ kan pàtó, tẹ ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ yẹn, kó o wá tẹ àmì àtẹ́tísí tó bá gbé wá.

  • Tó o bá fẹ́ gbọ́ àtẹ́tísí orí tó ò ń kà látìbẹ̀rẹ̀, tẹ bọ́tìnì Play tó wà lókè abala náà.

  • Tẹ bọ́tìnì Pause kó o lè dá a dúró.

  • Tẹ bọ́tìnì Ìṣúra kó o lè rí gbogbo àlàyé ìkẹ́kọ̀ọ́, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, atọ́ka, àwòrán àti fọ́tò tó wà ní orí náà ní Abala Ìkẹ́kọ̀ọ́. (Wàá ti rí abala yìí tó o bá ti ṣí orí kan.)

  • Tẹ bọ́tìnì Fi Bíbélì Wéra kó o lè rí bí àwọn Bíbélì míì ṣe túmọ̀ ẹsẹ kan ní Abala Ìkẹ́kọ̀ọ́.

  • Tẹ bọ́tìnì Atọ́ka kó o lè rí gbogbo atọ́ka orí yẹn tá a tò lẹ́sẹẹsẹ ní Abala Ìkẹ́kọ̀ọ́. Tó o bá fẹ́ ṣí Abala Ìkẹ́kọ̀ọ́ lórí àwọn fóònù tí ojú ẹ̀ ò tóbi, tẹ bọ́tìnì |<uF0DF>. Tó o bá fẹ́ fi Abala Ìkẹ́kọ̀ọ́ pa mọ́ lórí àwọn fóònù tí ojú ẹ̀ ò tóbi, tẹ bọ́tìnì |<uF0E0>.

Abala Ìṣúra

Ní abala Ìṣúra, wàá kọ́kọ́ rí àlàyé ṣókí tó dá lórí orí Bíbélì tó o ṣí. Tí àlàyé náà bá ní ìsọ̀rí, tẹ bọ́tìnì (+) kó o lè rí àwọn ìsọ̀rí náà tàbí kó o tẹ bọ́tìnì (-) kó o lè fi pa mọ́.

Lẹ́yìn náà, ní ẹsẹ kọ̀ọ̀kan, wàá rí:

  • Àlàyé ìkẹ́kọ̀ọ́: Ohun tó o lè kọ́ ní ẹsẹ yẹn.

  • Àwòrán tàbí fídíò: Àwọn àwòrán tàbí fídíò tó wà ní ẹsẹ yẹn. Tẹ àwòrán kan tàbí àlàyé ẹ̀ kó o lè ṣí Media Gallery kó o sì kẹ́kọ̀ọ́ sí i.

  • Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé: Àlàyé sí i lórí àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ yẹn.

  • Atọ́ka: Àwọn atọ́ka tá a so mọ́ ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ kan. Tẹ àmì (+) kó o lè rí gbogbo ẹ̀, kó o sì rí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà. Tẹ àmì (-) kó o lè pa á dé pẹ̀lú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà.

Abala Ìkàwé, tẹ nọ́ńbà tó wà níwájú ẹsẹ kan àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé tàbí álífábẹ́ẹ̀tì tá a fi ṣe atọ́ka kó o lè rí àwon ìsọfúnni lórí ẹsẹ yẹn ní Abala Ìkẹ́kọ̀ọ́.

Fi Bíbélì Wéra

Tó o bá tẹ bọ́tìnì Fi Bíbélì Wéra, wàá rí báwọn ìtúmọ̀ Bíbélì míì ṣe túmọ̀ ẹsẹ yẹn. Tẹ nọ́ńbà ẹsẹ míì ní Abala Ìkàwé kó o lè rí i báwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì ṣe túmọ̀ ẹsẹ yẹn.

Atọ́ka

Tó o bá tẹ bọ́tìnì Atọ́ka, wàá rí gbogbo atọ́ka tó wà ní orí Bíbélì tó ò ń kà, a pín àwọn atọ́ka náà sí ìsọ̀rí mẹ́ta:

  1. Àwọn Tó Jọ Ọ́: Àwọn atọ́ka yìí máa tọ́ka sí ìsẹ̀lẹ̀ kan náà nínú ìwé Bíbélì míì tàbí orí míì.

  2. Ọ̀rọ̀ Tá A Fà Yọ: Àwọn ẹsẹ Bíbélì míì tá a fa ọ̀rọ̀ yọ látinú rẹ̀ ní orí yẹn.

  3. Àwọn Míì: Àwọn atọ́ka tí kò jọra tàbí tí kì í ṣe ọ̀rọ̀ tá a fà yọ. Ó lè jẹ́ èyí tá a fi tọ́ka sí ẹnì kan náà tabí ibì kan náà, ó lè jẹ́ gbólóhùn kan náà tí wọ́n lò níbòmíì, ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ kan tàbí àlàyé nípa ìlànà kan tó tan mọ́ ọ̀rọ̀ náà.

Tẹ àmì (+)kó o lè rí gbogbo ẹ̀, kó o sì rí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà, tàbí kó o tẹ àmì (-) kó o lè pa á dé pẹ̀lú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà.

Sàmì sí àpótí Highlight All tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìsọ̀rí kan kó o lè rí gbogbo atọ́ka tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí yẹn ní Abala Ìkẹ́kọ̀ọ́. Bí àpẹẹrẹ, èyí máa wúlò tó o bá fẹ́ mo ibi tí ẹni tó kọ ìwé kan nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ti fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù.

Wo Àwòrán àti Fídíò Tó Wà Nínú Ìwé Bíbélì Kan

Ní apá Media Gallery, wàá rí àwọn àwòrán àti fídíò tó jẹ mọ́ ìwé Bíbélì kọ̀ọ̀kan. Ṣe la tò wọ́n tẹ̀ léra bá a ṣe tọ́ka sí wọn ní orí kọ̀ọ̀kan nínú ìwé náà.

 Ọ̀nà méjì wà tó o lè gbà dé Media Gallery:

  • Tẹ àwòrán kan ní Abala Ìkẹ́kọ̀ọ́.

  • Ní abala Table of Contents tàbí níbi àpótí tó wà lókè, yan Media. Tẹ àwòrán tàbí ìlujá ìwé Bíbélì kan.

Media Gallery ní apá mẹ́ta:

  1. Fídíò tàbí àwòrán náà. Tẹ bọ́tìnì < tàbí > kó o lè rí àwòrán tó ṣáájú tàbí èyí tó kàn.

  2. Àkọlé tó ń ṣàlàyé àwòrán náà, tó sì ní àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ míì tá a tọ́ka sí ní Abala Ìkẹ́kọ̀ọ́.

    Lórí àwọn fóònù tí ojú rẹ̀ ò fẹ̀, tẹ bọ́tìnì Fi Àkọlé Hàn kó o lè rí àkọlé àwòrán náà.

  3. Àwọn fọ́tò kéékèèké tá a tò sísàlẹ̀ tó tọ́ka sí àwọn àwòrán àti fídíò tó wà nínú ìwé Bíbélì kan. Tẹ bọ́tìnì < tàbí > kó o lè rí àwọn àwòrán míì. Tẹ fọ́tò kan kó o lè rí àwòrán tàbí fídíò tá a fi tọ́ka sí.

Tó o bá ti yan àwòrán kan, o lè fi bọ́tìnì Zoom In àti Zoom Out ṣe é kó tóbi tàbí kó pa dà sí bó ṣe wà, o sì lè fi ìka méjì ṣe é lójú fóònù ẹ tó bá máa ṣiṣẹ́.

Tó o bá ti yan fídíò kan, o lè máa wò ó tàbí kó o dá a dúró, o sì lè ṣe é kó gba gbogbo ojú fóònù ẹ.

Lo Àlàyé Ṣókí, Àlàyé Ọ̀rọ̀ Tàbí Àfikún Ìwé Bíbélì Kan

Ọ̀nà méjì wà tó o fi lè débi àwọn atọ́ka yìí:

  •   Tẹ ìlujá atọ́ka kan ní Abala Ìkẹ́kọ̀ọ́.

  • Yan ọ̀kan lára àwọn àpilẹ̀kọ yìí lábẹ́ Table of Contents tàbí níbi àpótí tó wà lókè.

Àwọn àlàyé ṣókí nípa ìwé Bíbélì ṣeé ṣí tàbí pa dé. Tẹ àmì (+) kó o lè ṣí ìsọ̀rí kan láti rí àwọn kókó tó wà níbẹ̀, àbí kó o tẹ àmì (-) kó o lè pa á dé pẹ̀lú àwọn ìsọfúnni tó wà níbẹ̀.

Apá tá a pè ní Àlàyé ọ̀rọ̀ ní àwọn ọ̀rọ̀ tó fara hàn nínú Bíbélì àti ìtumọ̀ wọn. Tó o bá tẹ ìlujá àlàyé ọ̀rọ̀ ní Abala Ìkẹ́kọ̀ọ́, ó máa gbé ẹ lọ síbẹ̀ gangan.

Tó bá jẹ́ Table of Contents tàbí àpótí tó wà lókè lo gbà dé àlàyé ọ̀rọ̀, yan lẹ́tà kan nínú àwọn álífábẹ́ẹ̀tì tá a tò tẹ̀ léra kó o lè rí ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ tó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú álífábẹ́ẹ̀tì yẹn, kó o wá lo sísàlẹ̀ láti wá èyí tó o fẹ́.

Àwọn àfikún kan ṣeé ṣí lọ́nà méjì—bí àwòrán kan (bó ṣe wà nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti orí ìwé) tàbí bí ọ̀rọ̀ tó ní àwòrán lọ́tọ̀.

  • Ṣí àpilẹ̀kọ náà bí àwòrán. Tẹ àwòrán náà kó o lè ṣí i. O lè fi bọ́tìnì Zoom In àti Zoom Out ṣeé kó tóbi tàbí kó kéré, o sì lè fi ìka méjì ṣe é lójú fóònù ẹ tó bá máa ṣiṣẹ́.

  • Ṣí àpilẹ̀kọ náà bí ọ̀rọ̀ tó ní àwòrán lọ́tọ̀. Èyí máa jẹ́ kó o lè tẹ ìlujá àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tàbí àwọn atọ́ka míì, kó o sì rí i ní Abala Ìkẹ́kọ̀ọ́.