ÌKÀNNÌ JW.ORG
Bó O Ṣe Lè Wá Nǹkan ní Èdè Míì
Tó o bá ń kọ́ èdè míì tàbí tó o fẹ́ fi ìsọfúnni tó wà lórí ìkànnì jw.org han ẹni tó ń sọ èdè míì, lo ọ̀kan nínú ọ̀nà mẹ́ta tá a tò sísàlẹ̀ yìí láti wá èdè tó o fẹ́.
Yí èdè tó o fi ń wo ìkànnì pa dà
Tẹ àmì Èdè kó o lè rí gbogbo èdè tó wà lórí jw.org.
Lọ́wọ́ òsì orúkọ èdè kọ̀ọ̀kan, wàá rí ọ̀kan nínú àwọn àmì mẹ́ta yìí:
Ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé a ti túmọ̀ ìkànnì náà tàbí apá kan lára rẹ̀ sí èdè yìí. Tẹ èdè náà kó lè jẹ́ òun ni wàá fi máa ṣí ìkànnì náà.
Ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé a ò tíì túmọ̀ ìkànnì náà sí èdè yìí, àmọ́ ìwé wà ní èdè yìí tó o lè wà jáde. Yan èdè náà kó o lè rí àwọn ìtẹ̀jáde tó wà.
Ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé èdè àwọn adití nìyí.
Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ohun tó wà fún èdè àwọn adití ló jẹ́ fídíò
Tẹ àpótí Èdè Àwọn Adití Nìkan kó o lè rí kìkì èdè adití nìkan.
Torí pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè ló wà lórí ìkànnì wa, lo ọ̀kan lára àwọn àbá yìí kó o lè tètè rí èdè tó ò ń wá:
Yan èdè kan láàyò: Èdè mẹ́rin tó o yàn lẹ́nu àìpẹ́ yìí ló máa wà lókè pátápátá.
Tẹ orúkọ èdè náà: O lè fi álífábẹ́ẹ̀tì èdè ẹ tàbí ti èdè tó ò ń wá tẹ orúkọ èdè náà. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé Gẹ̀ẹ́sì lo fi ṣí ìkànnì náà, tó o wá fẹ́ yí i pa dà sí German, o lè tẹ “German” tàbí “Deutsch.” Bó o ṣe ń tẹ ọ̀rọ̀ lọ láá máa dín èsì tó ń gbé wá kù sí àwọn èyí tó bá ọ̀rọ̀ tó o tẹ̀ mu.
Ṣí abala kan lórí ìkànnì ní èdè míì
Ọ̀nà 1: Lo àbá yìí ní àwọn abala tó ní àpótí Yan Èdè Tó O Fẹ́.
Lọ sí àpilẹ̀kọ tó o fẹ́ kà tàbí tó o fẹ́ fi ránsẹ́ sí ẹnì kan. Kó o wá yan èdè kan nínú àpótí Yan Èdè Tó O Fẹ́ kó o lè rí àpilẹ̀kọ náà ní èdè yẹn. (Tí èdè tó ò ń wá ò bá sí lára àwọn èdè tó wà nínú àpótí Yan Èdè Tó O Fẹ́, a jẹ́ pé àpilẹ̀kọ náà ò tíì sí ní èdè yẹn nìyẹn.)
Àbá: Nínú àpótí Yan Èdè Tó O Fẹ́, tó o bá rí àmì àtẹ́tísí lẹ́gbẹ̀ẹ́ òsì orúkọ èdè kan, ó túmọ̀ sí pé àtẹ́tísí àpilẹ̀kọ náà wà ní èdè yẹn.
Tó o bá lo àpótí Yan Èdè Tó O Fẹ́ láti ṣí àpilẹ̀kọ kan ní èdè míì, àpilẹ̀kọ yẹn nìkan ni èdè ẹ̀ máa yí pa dà. Gbogbo ibi tó kù lórí ìkànnì náà máa jẹ́ èdè tó ò ń lò tẹ́lẹ̀.
Ọ̀nà 2: Tí àpilẹ̀kọ tó ò ń kà ò bá ní àpótí Yan Èdè Tó O Fẹ́, lo àmì Èdè láti yí èdè ìkànnì náà pa dà sí èdè tó o fẹ́. Tí àpilẹ̀kọ tó ò ń kà bá wà ní èdè tó o yàn, o máa rí i. Tí kò bá sí, ó máa gbé ẹ lọ sí abala ìbẹ̀rẹ̀ ní èdè tó o yàn.
Wá ìtẹ̀jáde ní èdè míì
Lọ sí OHUN TÁ A NÍ. Yan Èdè kan lára àwọn èdè tó gbé wá.
Torí pé èdè tó wà níbẹ̀ pọ̀ gan-an, ó lè tẹ àmì Èdè, kó o wá bẹ̀rẹ̀ sí i tẹ orúkọ èdè ti ò ń wá, ó máa gbé ìwọ̀nba èdè tó bá ohun tó ò ń tẹ̀ mu jáde.
Tí ìtẹ̀jáde bá pọ̀ ní èdè tó o yàn, abala OHUN TÁ A NÍ ò ní gbé gbogbo ẹ̀ wá. Tó o bá fẹ́ rí gbogbo ìtẹ̀jáde tó wà ní èdè tó o yàn, lọ sí àwọn ìsọ̀rí kan pàtó (bí àpẹẹrẹ, ÌWÉ ŃLÁ ÀTI ÌWÉ PẸLẸBẸ tàbí ÌWÉ ÌRÒYÌN) kó o lè rí àwọn ìtẹ̀jáde tó wà ní èdè tó o yàn.
Tí kò bá sírú àwọn ìtẹ̀jáde bẹ́ẹ̀ ní èdè tó o yàn, ìlujá àwọn ìtẹ̀jáde tó wà lo máa rí ní abala yẹn.