JW LANGUAGE
Ìrànlọ́wọ́ Lórí Android
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ètò ìṣiṣẹ́ JW Language láti máa fi ran àwọn tó ń kọ́ èdè lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ gbọ́ èdè náà, kí wọ́n sì lè lò ó lóde ìwàásù àti nínú ìjọ.
Ohun Tuntun Tó Wà ní Version 2.5
Ìsọ̀rí Grammar: Wo bí oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ ṣe máa ń pinnu bó o ṣe máa hun ọ̀rọ̀, kó o lè mọ òfin ẹ̀hun gbólóhùn nínú èdè tó ò ń kọ́. Yí àwọn ọ̀rọ̀ inú gbólóhùn kan pa dà láti ọ̀rọ̀ ẹlẹ́ni kan sí ẹlẹ́ni púpọ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Jọ̀ọ́ Fi Sọ́kàn Pé:
Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, kọ̀ǹpútà ò ní lè fi álífábẹ́ẹ̀tì òde òní kọ ọ̀rọ̀ lábẹ́ ìsọ̀rí Grammar.
Ohun tó o ti ṣe ní apá text-to-speech lórí fóònù ẹ ló máa pinnu bí àtẹ́tísí tó wà lábẹ́ Grammar ṣe máa rí, torí náà, o lè ṣètò bó o ṣe fẹ́ kí èdè àti àtẹ́tísí rí lórí fóònù ẹ.
Ìsọ̀rí Grammar ò tíì sí ní èdè Arabic àti Low German.
NÍ APÁ YÌÍ
Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Máa Ń Béèrè—JW Language (Lórí Android)
Wo ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tí àwọn èèyàn sábà máa ń béèrè.