AUGUST 5, 2021
RỌ́ṢÍÀ
Ó Ṣeé Ṣe Kí Wọ́n Fi Arákùnrin Dmitriy Terebilov Sẹ́wọ̀n Fúngbà Àkọ́kọ́ Torí Ohun Tó Gbà Gbọ́ Lẹ́yìn Tó Ti Ṣẹ̀wọ̀n Lẹ́ẹ̀mẹ́rin
Déètì Ìṣẹ̀lẹ̀
Ní September 6, 2021, ilé ẹjọ́ agbègbè Sverdlovskiy nílùú Kostroma ní kí Arákùnrin Dmitriy Terebilov lọ sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́ta. Ojú ẹsẹ̀ tí wọ́n kéde ìdájọ́ náà ni wọ́n fi sínú àhámọ́
September 8, 2020
Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ẹjọ́ ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tí wọ́n fi kan Dmitriy
May 25, 2020
Wọ́n fẹ̀sùn kan Dmitriy, wọ́n sì ní kò gbọ́dọ̀ rìnrìn àjò
September 19, 2019
Wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé àkáǹtì tí Dmitriy ní sí báńkì
June 13, 2019
Wọ́n fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kan Dmitriy, wọ́n ní ó ń fún àwọn èèyàn ní ìwé tí ìjọba ti fòfin dè àti pé ó ń kópa nínú ìpàdé àwọn èèyàn tí ìjọba ti fòfin dè
July 25, 2018
Àwọn agbófinró lọ tú ilé Dmitriy kí òun àti ìyàwó ẹ̀ tó dé láti àpéjọ àgbègbè tí wọ́n lọ ṣe lórílẹ̀-èdè Moldova. Lẹ́yìn tí wọ́n délé, àwọn ọlọ́pàá mú wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò
Ìsọfúnni Ṣókí
Bí Dmitriy ṣe túbọ̀ ń ní irú ayọ̀ téèyàn máa ń ní torí pé ‘wọ́n ń gàn án nítorí orúkọ Kristi,’ ó dá wa lójú pé ‘ẹ̀mí ògo, àní ẹ̀mí Ọlọ́run, máa bà lé e.’—1 Pétérù 4:14.