DECEMBER 23, 2021
RỌ́ṢÍÀ
Arákùnrin Vitaliy Sukhov Rí Ọwọ́ Jèhófà Láyé Rẹ̀ Bí Àwọn Ará Ṣe Ràn Án Lọ́wọ́
LÁÌPẸ́ YÌÍ | Ní March 1, 2022, ilé ẹjọ́ Krasnoyarsk Territory Court wọ́gi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Arákùnrin Vitaliy Sukhov pè, wọn ò sì yí ìdájọ́ tí wọ́n ṣe tẹ́lẹ̀ pa dà. Kò ní lọ sẹ́wọ̀n lásìkò yìí.
Déètì Ìṣẹ̀lẹ̀
December 21, 2021
Ilé ẹjọ́ Zheleznodorozhny District Court ti ìlú Krasnoyarsk dá ẹjọ́ Vitaliy, wọ́n sì ní kó lọ lo ọdún mẹ́fà tó yẹ kó lò lẹ́wọ̀n nílé. Wọ́n á sì máa ṣọ́ ọ lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀ fọ́dún mẹ́ta
March 25, 2021
Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀
October 16, 2020
Ilé ẹjọ́ gbẹ́sẹ̀ lé ọkọ̀ rẹ̀
May 21, 2020
Wọ́n tú ilé Sukhov
May 8, 2020
Àwọn aláṣẹ fẹ̀sùn kan Vitaliy pé ó ń ṣètò ìpàdé ẹ̀sìn àwọn tí ìjọba ti fòfin dè
Ìsọfúnni Ṣókí
Ọkàn wa balẹ̀ bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà máa ń “ti àwọn olódodo lẹ́yìn,” ó sì mọ ohun tí wọ́n ń bá yí.—Sáàmù 37:17, 18.