Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Wọ́n dáná sun ilé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ní Lutsino, lágbègbè ìlú Moscow

JUNE 16, 2017
RỌ́ṢÍÀ

Ẹjọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Dá Ń Ní Ipa tí Kò Dáa Lórí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Ẹjọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Dá Ń Ní Ipa tí Kò Dáa Lórí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà ṣe ní April 20, 2017 ń ní ipa tó lágbára lórí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Àwọn aláṣẹ ń tẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn táwọn Ẹlẹ́rìí ní lójú, wọ́n sì ń mú wọn ní ọ̀daràn torí pé wọ́n ń jọ́sìn Ọlọ́run. Lẹ́sẹ̀ kan náà, àwọn ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà kan gbà pé ṣe ni ìpinnu tí ilé ẹjọ́ ṣe yìí fún àwọn láṣẹ láti máa ṣe ẹ̀tanú ẹ̀sìn sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kódà, ìkórìíra ń mú kí wọ́n máa ṣe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níkà.

Bí Ìjọba Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà Ṣe Ń Fi Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Du Aráàlú, Tí Wọ́n sì Ń Fìyà Jẹ Wọ́n

Dennis Christensen

Wọ́n Fẹ̀sùn Ọ̀daràn Kan Àwọn Òjíṣẹ́ Tó Jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà

  • Ní May 25, àwọn ọlọ́pàá ya wọ ibi tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Ìjọ Oryol ti ń ṣèpàdé. Àwọn ọlọ́pàá mú Dennis Christensen tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Denmark, tó sì jẹ́ alàgbà nínú Ìjọ Oryol. Wọ́n ti fi Ọ̀gbẹ́ni Christensen sí àtìmọ́lé di July 23 tí wọ́n máa gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀. Ṣe ni àwọn tó pè é lẹ́jọ́ ń fi àsìkò yìí wá bí wọ́n ṣe máa rojọ́ mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ pé “agbawèrèmẹ́sìn” ni. Tí ilé ẹjọ́ bá dá Ọ̀gbẹ́ni Christensen lẹ́bi, wọ́n lè rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà sí mẹ́wàá.

Àwọn Aláṣẹ Kìlọ̀ fún Àwọn Tó Ń Bójú Tó Ibi Táwọn Ẹlẹ́rìí Ti Forúkọ Ẹ̀sìn Wọn Sílẹ̀ Lábẹ́ Òfin

  • Ní May 4, ọ́fíìsì agbẹjọ́rò kìlọ̀ fún ẹni tó jẹ́ alága níbi táwọn Ẹlẹ́rìí ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin nílùú Krymsk. Wọ́n sọ pé ìjọba lè fìyà jẹ òun àtàwọn yòókù tí wọ́n jọ wà nínú ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó ibẹ̀, wọ́n sì lè fẹ̀sùn ọ̀daràn kàn wọ́n torí pé wọ́n ń ṣèjọsìn.

  • Látìgbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti dájọ́, ó kéré tán, ibi márùn-ún míì táwọn Ẹlẹ́rìí ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ ló ti gba irú ìkìlọ̀ yìí.

Àwọn Ọlọ́pàá Ya Wọ Ibi tí Wọ́n Ti Ń Jọ́sìn

  • Ní April 22, àwọn ọlọ́pàá wọ ilé tí àwọn Ẹlẹ́rìí ti ń jọ́sìn nílùú Dzhankoy, ní Republic of Crimea. Bí ìjọsìn tí wọ́n ń ṣe ṣe ń parí lọ làwọn ọlọ́pàá dé. Àwọn ọlọ́pàá náà yarí pé látìgbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti dájọ́ wọn, àwọn Ẹlẹ́rìí ò lẹ́tọ̀ọ́ láti pàdé pọ̀ fún ìjọsìn mọ́. Wọ́n wá tú inú ilé náà, wọ́n sì tì í pa kí àwọn Ẹlẹ́rìí má bàa jọ́sìn níbẹ̀ mọ́.

  • Látìgbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti dájọ́, ó kéré tán, ìgbà márùn-ún míì làwọn ọlọ́pàá ti ṣèdíwọ́ nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí ń jọ́sìn. Ìgbà kan wà nínú ìgbà márùn-ún yìí tó jẹ́ pé inú ilé ẹnì kan ni wọ́n ti ń ṣèjọsìn.

“Bí wọ́n ṣe ń fẹ̀sùn ọ̀daràn kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà láìnídìí yìí ń kó ìrònú bá mi gan-an, bẹ́ẹ̀ sì rèé, èèyàn àlàáfíà ni wọ́n láwùjọ. . . . Mo rọ àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà pé kí wọ́n má fi ẹ̀tọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní dù wọ́n, kí wọ́n jẹ́ kí wọ́n lómìnira ẹ̀sìn àti òmìnira láti gba ohun tó wù wọ́n gbọ́, kí wọ́n jẹ́ kí wọ́n lómìnira èrò àti ọ̀rọ̀ sísọ àti òmìnira láti kóra jọ pẹ̀lú àwọn míì ní ìrọwọ́rọsẹ̀, torí pé wọ́n gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé òfin tí ìjọba àpapọ̀ lágbàáyé ṣe lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, wọ́n sì ti tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn lọ́dọ̀ àjọ OSCE [ìyẹn Organization for Security and Cooperation in Europe].”—Michael Georg Link, Alága Àjọ OSCE Office for Democratic Institutions and Human Rights.

Wọ́n Dájú Sọ Àwọn Ọmọ Iléèwé Tó Jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà

  • Ní April 24, nílùú Bezvodnoye, lágbègbè Kirov, olùkọ́ kan kan àwọn ọ̀dọ́ méjì tí ìyá wọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lábùkù. Ṣe ni olùkọ́ yẹn tún ń dára rẹ̀ láre fún ohun tó ṣe, ó ní ìjọba kúkú ti fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà.

  • Ní May 17, lágbègbè ìlú Moscow, ọ̀gá iléèwé kan kọ̀wé sí àwọn òbí ọmọ ọlọ́dún mẹ́jọ kan láti kìlọ̀ fún wọn, torí pé ọmọ yìí sọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún ọmọ kíláàsì rẹ̀ kan. Nínú lẹ́tà yẹn, ọ̀gá náà sọ̀rọ̀ ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ṣe, ó sì sọ pé níléèwé àwọn, kò sáyè “láti ṣe ohunkóhun tó bá ti yàtọ̀ sí ti ẹ̀kọ́ ìwé.” Ọ̀gá náà sọ pé òun máa gbé ọ̀rọ̀ náà dé ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́pàá, òun sì máa “sọ pé kí wọ́n gbé ọmọ náà kúrò níléèwé, kí wọ́n fi sẹ́nu iṣẹ́ míì.”

Wọn Ò Gbà Kí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tó Jẹ́ Ọkùnrin Ṣiṣẹ́ Àṣesìnlú

  • Ní April 28, àjọ tó ń fa àwọn èèyàn wọṣẹ́ ológun lágbègbè Cheboksary àti Marposadskiy fagi lé ìwé tí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan kọ pé kí wọ́n jẹ́ kóun ṣiṣẹ́ àṣesìnlú dípò iṣẹ́ ológun. Àjọ náà sọ pé “agbawèrèmẹ́sìn” làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn ò sì lè gbà kí wọ́n ṣiṣẹ́ àṣesìnlú.

  • Ó kéré tán, ọkùnrin méjì míì tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ni àwọn aláṣẹ ò gbà kí wọ́n ṣiṣẹ́ àṣesìnlú.

Philip Brumley, tó jẹ́ agbẹjọ́rò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kíyè sí i pé ohun tí ìjọba ń ṣe ta kora, ó ní: “Ìjọba ò gbà káwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣiṣẹ́ àṣesìnlú torí wọ́n sọ pé ‘agbawèrèmẹ́sìn’ ni wọ́n. Ìjọba yìí kan náà ló tún sọ pé káwọn èèyàn tí wọ́n pè ní ‘agbawèrèmẹ́sìn’ yìí wá wọṣẹ́ ológun. Ṣé ó wá bọ́gbọ́n mu kí ìjọba gbà kí àwọn ‘agbawèrèmẹ́sìn’ yìí dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun?”

Wọ́n Ń Hùwà Àìdáa sí Wọn Láwùjọ, Wọ́n sì Ń Ṣe Ẹ̀tanú Wọn

Àwọn Èèyàn Hùwà Ipá Sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

  • Ní April 30, ní Lutsino, lágbègbè ìlú Moscow, wọ́n sun ilé tó jẹ́ ti ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan kanlẹ̀, wọ́n tún sun ilé àwọn òbí wọn àgbà tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibẹ̀. Ẹni tó dáná sun àwọn ilé yìí ti kọ́kọ́ bá àwọn ìdílé yìí fà á, pé òun kórìíra ẹ̀sìn wọn, kó tó wá dáná sun ilé méjèèjì.

  • Ní May 24, ní Zheshart, lágbègbè Komi Republic, àwọn kan dáná sun ilé kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń jọ́sìn, ilé náà sì bà jẹ́ gan-an.

    Wọ́n dáná sun Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní Zheshart

  • Ó kéré tán, ilé mẹ́sàn-án míì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń jọ́sìn làwọn èèyàn ti bà jẹ́ látìgbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti dájọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí ní April 20, 2017.

  • Ní April 26, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Belgorod ń jáde nílé, ni ẹnì kan bá kígbe pé, “Wọ́n ti fòfin de ẹ̀yin ajẹ́rìí!” ló bá mú Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà, ó sì lù ú.

  • Ní May 11, àwùjọ àwọn ọkùnrin kan ya wọ ibi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń jọ́sìn nílùú Tyumen, wọ́n sì sọ̀rọ̀ burúkú sí àwọn tó wà níbẹ̀, wọ́n halẹ̀ mọ́ wọn pé àwọn máa ṣe wọ́n léṣe.

Wọ́n Lé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kúrò Níbi Iṣẹ́

  • Ní May 15, àwọn ọ̀gá iléeṣẹ́ kan tí wọ́n ti ń po kẹ́míkà ní Dorogobuzh, lágbègbè Smolensk lé gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n gbà síṣẹ́ kúrò níbi iṣẹ́. Iléeṣẹ́ náà ṣàlàyé pé àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Ìjọba ló pàṣẹ fáwọn pé káwọn lé gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kúrò níbi iṣẹ́ torí pé “àwọn agbawèrèmẹ́sìn” ò lè ṣiṣẹ́ ní iléeṣẹ́ náà.

  • Látìgbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti dájọ́, ó kéré tán, ẹ̀ẹ̀mẹta làwọn ọ̀gá iléeṣẹ́ ti halẹ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n gbà síṣẹ́ pé àwọn máa lé wọn níbi iṣẹ́ torí wọ́n gbà pé ẹ̀sìn “agbawèrèmẹ́sìn” ni wọ́n ń ṣe. Nílùú Yashkino, lágbègbè Kemerovo, àwọn ọlọ́pàá fúngun mọ́ obìnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó lè fún wọn ní ìsọfúnni nípa àwọn Ẹlẹ́rìí míì, àmọ́ ó kọ̀, kò fún wọn. Àwọn ọlọ́pàá náà sọ pé kò bófin mu kéèyàn máa ṣe ẹ̀sìn tí ìjọba ti fòfin dè, wọ́n tiẹ̀ fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wé àwọn apániláyà tí wọ́n ń pè ní ISIS.

Ọkàn Ò Balẹ̀ Lórí Ọ̀rọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà

Ní ọdún mẹ́wàá tó ṣáájú àkókò tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ dájọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà, ìjọba ti ń fúngun mọ́ wọn lórí ọ̀rọ̀ òmìnira ẹ̀sìn débi pé èyí mú káwọn èèyàn fìyà jẹ wọ́n gan-an. Ní báyìí tí ilé ẹjọ́ tiẹ̀ ti wá dájọ́, ààbò wọn ò dájú mọ́. Ìpinnu tí ilé ẹjọ́ ṣe yìí ń ba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórúkọ jẹ́, ó sì ti jẹ́ káwọn èèyàn kan àtàwọn òṣìṣẹ́ ìjọba túbọ̀ máa fìyà jẹ wọ́n, àpẹẹrẹ rẹ̀ la rí nínú àwọn ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀ yìí. Gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ló ń ronú gan-an nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Rọ́ṣíà tí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Gbọ́ Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ bá lọ dá wọn lẹ́bi nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ẹjọ́ wọn ní July 17, 2017.

Ọ̀gbẹ́ni Brumley sọ pé: “A ò tíì rí ẹ̀rí kankan, bó ti wù kó kéré mọ, látọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni tó lè tọ́ka sí i pé agbawèrèmẹ́sìn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n ń sọ pé eléwu èèyàn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ láàárín ìlú, àmọ́ ewu èyíkéyìí tí wọn ì báà sọ pé wọ́n ń fà kò tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ohun táwọn èèyàn ti fojú wọn rí. Ó yẹ kí ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà tún èrò wọn pa lórí ohun tí wọ́n ń ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí, pàápàá torí pé òfin ilẹ̀ wọn fọwọ́ sí i pé àwọn aráàlú lómìnira ẹ̀sìn, wọ́n sì ti tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn lọ́dọ̀ ìjọba àpapọ̀ lágbàáyé pé àwọn ò ní fi òmìnira ẹ̀sìn du ẹnikẹ́ni.”