Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JUNE 28, 2017
RỌ́ṢÍÀ

Ilé Ẹjọ́ Fagi Lé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tí Dennis Christensen Pè Lórí Bí Wọ́n Ṣe Fi sí Àtìmọ́lé

Ilé Ẹjọ́ Fagi Lé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tí Dennis Christensen Pè Lórí Bí Wọ́n Ṣe Fi sí Àtìmọ́lé

Ní June 21, 2017, Ilé Ẹjọ́ Ìlú Oryol fagi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Dennis Christensen pè lórí bí wọ́n ṣe fi sí àtìmọ́lé láìtíì gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀. May 25, 2017 ni wọ́n mú Ọ̀gbẹ́ni Christensen tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Denmark. Ṣe ni àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Ìjọba àtàwọn ọlọ́pàá tó fi nǹkan bojú, tí wọ́n sì dira ogun ya wọ ibi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣèpàdé lọ́jọ́ tá à ń wí yìí.

Ẹnu àìpẹ́ yìí ni Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà kéde pé iṣẹ́ “agbawèrèmẹ́sìn” làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe láwọn ibi tí wọ́n ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, ilé ẹjọ́ náà sì sọ pé káwọn Ẹlẹ́rìí dáwọ́ iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ dúró lójú ẹsẹ̀. Àwọn agbófinró tó ya wọ ibi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣèpàdé ní May 25 sọ fáwọn tó wà nípàdé náà pé àwọn máa fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ṣì ń ṣèjọsìn lẹ́yìn tí ìjọba ti fòfin de ọ́fíìsì wọn pé agbawèrèmẹ́sìn ni wọ́n. Àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Ìjọba sọ pé kí ilé ẹjọ́ fi Ọ̀gbẹ́ni Christensen sí àtìmọ́lé di July 23, 2017 kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀, kí wọ́n lè ráyè wá ẹ̀sùn fi kàn án lórí ọ̀rọ̀ pé ó ń ṣiṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, èèyàn àlàáfíà ni.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ẹjọ́ tí kò tọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ dá, wọ́n sì ń múra láti gbèjà ara wọn pé àwọn lẹ́tọ̀ọ́ láti máa jọ́sìn ní ìrọwọ́rọsẹ̀ láìsí ìdíwọ́, ó ṣe tán, Òfin Ilẹ̀ Rọ́ṣíà àti ìwé àdéhùn European Convention on Human Rights ṣe fọwọ́ sí i pé wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.