Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 1, 2012
AUSTRIA

Ilé Ẹjọ́ Ní Kí ìjọba Austria San Owó Máà-Bínú fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Ilé Ẹjọ́ Ní Kí ìjọba Austria San Owó Máà-Bínú fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

NÍ September 25, ọdún 2012, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù tó wà ní ìlú Strasbourg, ní orílẹ̀-èdè Faransé dájọ́ pé ìjọba Austria jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án pé ó ṣe ẹ̀tanú sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ilé ẹjọ́ yìí wá pàṣẹ pé kí ìjọba náà san owó tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá owó yúrò tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ṣe ẹjọ́ náà, èyí fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù méjì ààbọ̀ náírà (₦2,490,000).

Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé ní ọdún 2002, àwọn òjíṣẹ́ méjì tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti ilẹ̀ Philippines wá sí ilẹ̀ Austria kí wọ́n lè bẹ àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń sọ èdè Tagalog wò, àmọ́ ìjọba ilẹ̀ Austria sọ pé wọn kò lè dúró ní ìlú àwọn. Ṣáájú èyí, ìjọba yìí ti pàṣẹ pé kí àwọn Ẹlẹ́rìí san owó orí torí àwọn ọrẹ tí wọ́n gbà fún ẹ̀sìn wọn ní ọdún 1999. Ohun tó jẹ́ kí ìjọba lè ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe yìí ni pé kàkà kí wọ́n ka àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí “ẹ̀sìn tó fìdí múlẹ̀,” “ẹ̀sìn yẹpẹrẹ” ni wọ́n kà wọ́n sí, èyí túmọ̀ sí pé wọ́n rẹlẹ̀ lábẹ́ òfin. Èyí mú kí wọ́n máa fi àwọn àǹfààní kan tí wọ́n ń fún àwọn ẹ̀sìn míì tó ti fìdí múlẹ̀ du àwọn Ẹlẹ́rìí.

Èyí ni ìgbà kẹfà tí Ilé Ẹjọ́ yìí dá ìjọba Austria lẹ́bi tí wọ́n sì dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre, ó sì tún fẹsẹ̀ ẹjọ́ kan tí wọ́n dá ní ọdún 2008 múlẹ̀. Nígbà yẹn, Ilé Ẹjọ́ sọ pé ó ti yẹ kí ìjọba Austria ka àwọn Ẹlẹ́rìí sí “ẹ̀sìn tó fìdí múlẹ̀ tipẹ́tipẹ́” torí pé “ó pẹ́ tí gbogbo ayé ti mọ̀ wọ́n” àti pé “ó pẹ́ tí wọ́n ti wà” ní ilẹ̀ Austria.

Àwọn Ẹlẹ́rìí retí pé ẹjọ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ jàre rẹ̀ ní Ilé Ẹjọ́ Yúróòpù yìí ò ní jẹ́ kí wọ́n máa tẹ ẹ̀tọ́ àwọn lójú mọ́, á sì dáwọ́ ẹ̀tanú tí wọ́n ń ṣe sí ẹ̀sìn dúró. Èyí á ṣàǹfààní fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé àti fún gbogbo àwọn èèyàn tó ń gbé ní àwọn ilẹ̀ tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù.

Media Contacts:

J. R. Brown, Office of Public Information, tel. +1 718 560 5000

Austria: Johann Zimmermann, tel. +43 1 804 53 45