Àlàyé Ṣókí Nípa Azerbaijan
Ìlú Baku tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Azerbaijan ni wọ́n ti kọ́kọ́ forúkọ ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lọ́dún 1999, wọ́n sì gbà kí wọ́n tún forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ ní 2002. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lómìnira déwọ̀n àyè kan láti ṣe ẹ̀sìn wọn, àmọ́ ìjọba ò jẹ́ kí wọ́n rímú mí, bíi kí àwọn ọlọ́pàá máa dààmú wọn nínú ìpàdé tàbí kí wọ́n máa gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ìtẹ̀jáde wọn.
Ní May 2009, Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn (SCWRA) ṣàtúnṣe sí Òfin Òmìnira Ẹ̀sìn àti Ìgbàgbọ́. Àmọ́ nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ tún forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lọ́dún 2010, ìgbìmọ̀ SCWRA fagi lé ìwé táwọn Ẹlẹ́rìí kọ láti fi béèrè pé kí ìjọba tún forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀, èyí sì mú kí àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn yìí ní ìlú Baku pàdánù ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní lábẹ́ òfin. Ọ̀rọ̀ yìí mú kí wọ́n túbọ̀ máa fojú àwọn Ẹlẹ́rìí gbolẹ̀ torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́.
Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ yí pa dà lọ́dún 2015 nígbà tí ìgbìmọ̀ SCWRA jáwọ́ nínú bí wọ́n ṣe ń dí àwọn Ẹlẹ́rìí lọ́wọ́ láti máa kó àwọn ìtẹ̀jáde wọn wọlé. Bákan náà àwọn Ẹlẹ́rìí ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn àpéjọ ńlá látọdún 2016. Èyí tó wá lápẹẹrẹ jù ni pé, ní November 8, 2018, ìgbìmọ̀ SCWRA gba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyè láti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní ìlú Baku. A retí pé bí wọ́n ṣe forúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ ní ìlú Baku yìí máa ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún fíforúkọ wọn sílẹ̀ láwọn ìlú míì.
Àwọn ẹ̀tọ́ kan téèyàn ní láti ṣe ẹ̀sìn ṣì wà tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè Azerbaijan wà lára Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù (Council of Europe), ìjọba kọ̀ láti ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú míì dípò iṣẹ́ ológun. Torí náà, wọ́n máa ń fojú àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí gbolẹ̀, wọ́n sì máa ń fìyà jẹ wọ́n torí pé wọ́n kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun.
Kí ohun tójú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń rí láti ọ̀pọ̀ ọdún yìí lè tán nílẹ̀, wọ́n fi ẹjọ́ méjìdínlógún (18) sùn ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù, wọ́n sì fi ẹjọ́ mọ́kànlá (11) sùn lọ́dọ̀ Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lábẹ́ Ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Àwọn aṣojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣì ń bá àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Azerbaijan sọ̀rọ̀ kí wọ́n lè wá ojútùú sí ìṣòro tó wà nílẹ̀ yìí, kí wọ́n sì yéé fi ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní dù wọ́n láti ṣe ohun tí wọ́n gbà gbọ́.