SEPTEMBER 17, 2019
ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ
Iṣẹ́ Ìkọ́lé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Ti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Parí
Iṣẹ́ ìkọ́lé ẹ̀ka ọ́fíìsì ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó wà nítòsí Chelmsford, Essex ni a retí pé kó parí ní December 2019. Ní báyìí, àwọn ọ̀mọ̀wé gbà pé àpẹẹrẹ tó yẹ kí àwọn èèyàn tẹ̀ lé tó bá di pé ká sọ ilẹ̀ dọ̀tun ló jẹ́.
Oríṣiríṣi pàǹtírí làwọn èèyàn ń dà sí ilẹ̀ ọ̀hún títí kan àwọn mọ́tò tó ti bà jẹ́ kí àwọn ará wa tó ra ilẹ̀ náà ní 2015. Àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni ló hú àwọn ìdọ̀tí náà kúrò, wọ́n kó o dà nù, wọ́n sì tún àwọn kan tó ṣì lè wúlò ṣe, wọ́n tiẹ̀ hú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn táyà tọ́jọ́ wọ́n ti pẹ́ jáde níbẹ̀. Kódà àwọn táyà kan ti wà níbẹ̀ látìgbà Ogun Àgbáyé Kejì. Lẹ́yìn náà, wọ́n sẹ́ àwọn iyanrìn tó ti dọ̀tí, títí kan àwọn òkúta kéékèèké, wọ́n sì tún wọ́n ṣe fún lílò, wọ́n tiẹ̀ tún àwọn kan ṣe kí wọ́n lè lò wọ́n fún àwọn nǹkan míì. Kò tán síbẹ̀ o, wọ́n tún lo àwọn iyanrìn tó mọ́ náà fún iṣẹ́ ìkọ́lé. Ní àkópọ̀, ó lé ní ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá (11,000) àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láti ṣiṣẹ́ níbẹ̀, ó sì ju mílíọ̀nù mẹ́rin wákàtí lọ tí wọ́n fi ṣiṣẹ́ lórí ilẹ̀ hẹ́kítà mẹ́tàlélọ́gbọ̀n náà.
Tí wọ́n bá parí iṣẹ́ náà, ilẹ̀ náà máa ní ọgbà ọ̀gbìn tó rẹwà, adágún omi, onírúurú òdòdó ẹgàn àti ọgbà eléso tó jojú ní gbèsè. Kì í ṣe pé ilẹ̀ tó tẹ́jú yìí kàn dùn ún wò nìkan ni, ó tún jẹ́ ibùgbé fún àwọn ẹranko ìgbẹ́, ó mú kó rọrùn láti ṣọ́ omi lò, ibẹ̀ tún jẹ ibi tó dáa láti dá àwọn igi ńláńlá àti kéékèèké sí, èyí sì mú kí àwọn ewéko tó pọ̀ wà níbẹ̀, kó sì túbọ̀ mú kí àdúgbò náà rẹwà fún àwọn tó ń gbé ibẹ̀.
Arákùnrin Paul Rogers, tó jẹ́ ọkàn lára àwọn ìgbìmọ̀ ìkọ́lé sọ pé: “Ilẹ̀ ti wọ́n ò lò, tí wọ́n sì ti pa tì fún ọ̀pọ̀ ọdún la rà. Ilẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí jọjú nígbà tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni ń fara balẹ̀ ṣa àwọn ìdọ̀tí náà. Lẹ́yìn náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí palẹ̀ àwọn ìdọ̀tí náà mọ́, wọ́n ń tún ilẹ̀ náà ṣe ní ìbámu pẹ̀lú bí ilẹ̀ náà ṣe rí, wọ́n wá gbin onírúurú àwọn igi, igbó àtàwọn ewéko. Bí ilẹ̀ náà ṣe rẹwà lẹ́yìn tí wọ́n tún un ṣe rán wa létí ọ̀rọ̀ tó wà ní Ìsíkíẹ́lì 36:35, 36 tó sọ pé: ‘Àwọn èèyàn á sì sọ pé: “Ilẹ̀ tó ti di ahoro náà ti dà bí ọgbà Édẹ́nì” . . . Àwọn orílẹ̀-èdè . . . yóò wá mọ̀ pé, èmi Jèhófà ti kọ́ ohun tó ya lulẹ̀, mo sì ti gbin ohun tó ti di ahoro.’ ”
Àwọn arábìnrin méjì ń tún odò adágún kan tí ìdọ̀tí kún inú ẹ̀ ṣe. Onírúurú pàǹtí ló kún inú odò adágún yìí fọ́fọ́, ẹ̀rọ katakata ni wọ́n fi kó àwọn amọ̀ tó wà níbẹ̀ jáde nígbà tí wọ́n fi ọwọ́ kó àwọn pàǹtí kéékèèké, wọ́n sì fi ọwọ́ tu àwọn ewéko tí kò wúlò. O ju ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ [8,000] àwọn ewé odó tí wọ́n ti gbìn, èyí sì ń jẹ́ kí omi náà mọ́ tónítóní
Ọ̀kan lára odò adágún tá à ń darí omi sí. Omi tó wá láti ojú ọ̀nà tó wà nítòsí àti ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ló ń ṣàn lọ síbẹ̀. Apá òsì fọ́tò yìí fi ibùdókọ̀ kan tó wà nítòsí hàn níbi táwọn ara àdúgbò ti lè gbádùn ọgbà náà
Àwọn mẹ́ta tó ń mojú tó bí ilẹ̀ náà ṣe máa dún ún wò ń gbin igi. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15,000) igi, igbó ṣúúrú àtàwọn ewéko míì ni wọ́n ti gbìn síbẹ̀
Igi ólífì mẹ́fà, tí wọ́n fojú bù pé á ti lò tó ọgọ́rùn-ún ọdún ni wọ́n ti tún gbìn sí iwájú ibi tí ọ́fíìsì wà
Àwọn arábìnrin ń ya fọ́tò nígbà tí wọ́n ń ṣe àtúnṣe bí ilẹ̀ náà á ṣe dùn ún wò. Ó lé ní ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún (18,000) ọ̀wọ́ òdòdó tí wọ́n gbìn sí ibi tí àwọn igi wà. Ó kéré tán, mẹ́jọ nínú mẹ́wàá àwọn ewéko tí wọ́n gbìn síbi ló jẹ́ pé àwọn ewéko tó wà lágbègbè yìí náà ni wọ́n
Àwọn òdòdó, igbó ṣúúrú àtàwọn igi ni wọ́n fara balẹ̀ gbìn sí ẹnu ọ̀nà Ilé Gbígbé tí wọ́n ń pè ní Residence F