Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ń fáwọn èèyàn ní ìsọfúnni nípa bí wọ́n ṣe lè tọ́jú aláìsàn láìlo ẹ̀jẹ̀ níbi àpérò Joint Congress of the Scientific Societies of Surgery nílùú Róòmù

JUNE 27, 2019
ÍTÁLÌ

Ọ̀pọ̀ Dókítà Nífẹ̀ẹ́ sí Títọ́jú Aláìsàn Láìlo Ẹ̀jẹ̀ Níbi Àpérò Pàtàkì Méjì Táwọn Onímọ̀ Ìṣègùn Ṣe Lórílẹ̀-Èdè Ítálì

Ọ̀pọ̀ Dókítà Nífẹ̀ẹ́ sí Títọ́jú Aláìsàn Láìlo Ẹ̀jẹ̀ Níbi Àpérò Pàtàkì Méjì Táwọn Onímọ̀ Ìṣègùn Ṣe Lórílẹ̀-Èdè Ítálì

Àwọn dókítà ṣèbẹ̀wò síbi ìpàtẹ wa níbi àpérò SIAARTI tí wọ́n ṣe ni erékùṣù Palermo

Ọ̀pọ̀ dókítà ló ń dúpẹ́ lọ́wọ́ ètò wa torí ìsọfúnni tá a pèsè kárí ayé nípa onírúurú ìtọ́jú ìṣègùn àti iṣẹ́ abẹ láìfa ẹ̀jẹ̀ síni lára. Ẹ̀ka Tó Ń Pèsè Ìsọfúnni fún Àwọn Ilé Ìwòsàn (lórílẹ̀-èdè Ítálì), tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Róòmù wà lára ètò tá a dá sílẹ̀ kárí ayé. Ní October 10 sí 13, 2018, ẹgbẹ́ kan lórílẹ̀-èdè Ítálì tá a mọ̀ sí Italian Society of Anesthesia, Analgesia, Resuscitation, and Intensive Care (SIAARTI) ṣe àpérò kan nílùú Palermo ní erékùṣù Sísílì. Níbi àpérò náà, àwọn tó ń ṣojú fún Ẹ̀ka Tó Ń Pèsè Ìsọfúnni fún Àwọn Ilé Ìwòsàn (lórílẹ̀-èdè Ítálì) àtàwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn ṣètò ìpàtẹ kan. Lẹ́yìn tí wọ́n parí àpérò yẹn, àwọn arákùnrin wa tún gbé ìpàtẹ yẹn lọ síbi àpérò Joint Congress of the Scientific Societies of Surgery tí wọ́n ṣe ní gbọ̀ngàn àpérò “La Nuvola” nílùú Róòmù.

A máa ń lo àǹfààní àwọn àpérò yìí láti pèsè àwọn ìsọfúnni tuntun nípa ìtọ́jú ìṣègùn láìlo ẹ̀jẹ̀ fún gbogbo dókítà tó nífẹ̀ẹ́ sí i. Àwọn dókítà tó ń pa ìrora nígbà iṣẹ́ abẹ tí iye wọn tó ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (2,800) ló wá síbi àpérò tí wọ́n ṣe nílùú Palermo. Ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún (3,500) dókítà tó ń ṣiṣẹ́ abẹ ló wá síbi àpérò tí wọ́n ṣe nílùú Róòmù. Ó sì jọ pé àpérò àwọn dókítà tó ń ṣiṣẹ́ abẹ tó tíì gbòòrò jù lọ tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Ítálì nìyẹn. Àwọn aṣojú láwọn ilé ìwòsàn tó lórúkọ ló pésẹ̀ síbi àpérò náà. Títí kan gbogbo àwọn tó wà nínú ẹgbẹ́ tá a mọ̀ sí Italian associations of surgeons àti American College of Surgeons ti orílẹ̀-èdè Ítálì. Ọ̀pọ̀ ilé iṣẹ́ ló sì ti ètò náà lẹ́yìn, irú bí Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìlera.

Dókítà kan tó ń jẹ́ Vincenzo Scuderi láti Ilé Ìwòsàn Policlinico ti Catania ní erékùṣù Sísílì, wá síbi ìpàtẹ wa níbi àpérò tí wọ́n ṣe nílùú Palermo. Ní January 18, 2019, dókítà náà ṣe iṣẹ́ abẹ pàjáwìrì fún Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ní àìsàn tí wọ́n ń pè ní aortic dissection. Dókítà náà ṣe iṣẹ́ abẹ tó díjú yìí láìlo ẹ̀jẹ̀. Dókítà Scuderi ṣàlàyé pé: “[Ìpàtẹ] tẹ́ ẹ ṣe níbi àpérò SIAARTI lọ́dún 2018 ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Àwọn ìsọfúnni tẹ́ ẹ fún wa sì gbéṣẹ́ gan an.”

Ní báyìí, àwọn dókítà tó ju ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) lórílẹ̀-èdè Ítálì ti gbà láti máa tọ́jú àwọn aláìsàn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà nípa lílo ìlànà ìtọ́jú ìṣègùn àti iṣẹ́ abẹ tí kò léwu, tó gbéṣẹ́, tí kò sì nílò ìfàjẹ̀sínilára. Lọ́dọọdún, ìpíndọ́gba àwọn aláìsàn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí iye wọn tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún (16,000) ló ń gba ìtọ́jú láìlo ẹ̀jẹ̀ lórílẹ̀-èdè Ítálì.