Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tí wọ́n tún ṣe ní ìlú Hiroshima.

NOVEMBER 7, 2018
JAPAN

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣèrànwọ́ Fáwọn Tí Omíyalé Dà Láàmú ní Japan

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣèrànwọ́ Fáwọn Tí Omíyalé Dà Láàmú ní Japan

Ó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínláàádọ́ta (47,000) àwọn ará wa tó ń gbé láwọn agbègbè tó wà ní ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Japan tí omíyalé ti ṣọṣẹ́ lóṣù July 2018. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn (4,900) tó yọ̀ǹda ara wọn láti ṣèrànwọ́ fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, wọ́n palẹ̀ ìdọ̀tí mọ́ kúrò nínú ilé àwọn ará àtàwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó bà jẹ́, wọ́n sì tún wọn ṣe.

Àwọn ará yọ̀ǹda ara wọn láti palẹ̀ ìdọ̀tí mọ́ kúrò nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà lókè.

Àwọn Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù ṣètò bí àwọn ará ṣe palẹ̀ ìdọ̀tí mọ́ kúrò nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́sàn-án tí omíyalé náà bà jẹ́, wọ́n sì tún àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba náà ṣe. Ní báyìí, àtúnṣe ń lọ lọ́wọ́ lórí Gbọ̀ngàn Ìjọba kan. Bákan náà, ilé mẹ́rìnlélọ́gọ́sàn-án (184) àwọn ará wa ni wọ́n ti parí àtúnṣe rẹ̀ tàbí tí wọ́n ti tún ṣe díẹ̀ kó lè ṣeé gbé, àwọn ilé mọ́kànlá míì sì wà tí wọ́n ṣètò láti tún ṣe lọ́dún yìí.

Àwòrán Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ṣáájú àti lẹ́yìn tí wọ́n tún un ṣe.

Àwòrán ìdílé Abe láti agbègbè Ehime lẹ́yìn táwọn ará parí títún ilé wọn tí omíyalé bà jẹ́ ṣe.

Ìdílé Taro àti Keiko Abe wà lára àwọn tí wọ́n ràn lọ́wọ́, ọmọ mẹ́ta ni wọ́n bí, agbègbè Ehime ni wọ́n sì ń gbé. Ọjọ́ mẹ́ta péré lẹ́yìn tí omíyalé ba ilé wọn jẹ́, àwọn ará láti àyíká ibẹ̀ dé, wọ́n sì tún ilé náà ṣe, kódà wọ́n tún ilẹ̀ ilé náà ṣe torí omíyalé ti bà á jẹ́. Kò mọ síbẹ̀ o, àwọn ará lágbègbè náà tún fún àwọn ọmọ wọn ní àwọn bẹ́ẹ̀dì àtàwọn tábìlì tuntun.

Ní September 20, 2018, Arákùnrin Geoffrey Jackson tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí wá sí orílẹ̀-èdè Japan fún iṣẹ́ kan, ó sì fìyẹn sọ àsọyé kan níbi ìpàdé àkànṣe láti fún àwọn ará níṣìírí, Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ní ìlú Okayama ni wọ́n ti ṣèpàdé náà. Àpapọ̀ iye àwọn ará tó wá sípàdé náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógójì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti mọ́kànléláàádọ́rùn-ún (36,691), lára wọn wá láti àwọn ibi tí ìjì líle àti ìmìtìtì ilẹ̀ ti ṣọṣẹ́ nígbà kan náà lẹ́nu àìpẹ́ yìí ní Japan, wọ́n gbọ́ bí Arákùnrin Jackson ṣe ṣàlàyé bí Jèhófà ṣe máa ń bójú tó àwọn èèyàn Rẹ̀, tó sì máa ń tù wọ́n nínú lásìkò wàhálà. Arákùnrin Jackson tún fi àsìkò náà bá ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tí àjálù náà kàn sọ̀rọ̀ ìtùnú.

Àwa àtàwọn ará wa ní Japan ń dúpẹ́ pé a wà nínú ètò Jèhófà, tó ń fìfẹ́ ṣe nǹkan, tó sì jẹ́ ká mọ bí ọ̀rọ̀ wa ṣe jẹ Baba wa ọ̀run lọ́kàn tó.—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.

Arákùnrin Geoffrey Jackson tó wà lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí wà pẹ̀lú arábìnrin kan ní Okayama tí omíyalé ti ba nǹkan jẹ́ ní ìwọ̀ oòrùn Japan lóṣù July 2018.