Kyrgyzstan
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Orílẹ̀-èdè Kyrgyzstan
-
Iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—5,167
-
Iye àwọn ìjọ—86
-
Iye àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi—10,146
-
Iye èèyàn tí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan máa wàásù fún—1,387
-
Iye èèyàn—7,038,000
Ṣé Àwọn tí Ọlọ́pàá Lù Nílùkulù Nílùú Osh Máa Jìyà Yìí Gbé Ni?
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bẹ Agbẹjọ́rò Àgbà pé kó gbé ìgbésẹ̀ tó tọ́, kó sì pe àwọn tó hùwà tó lè gbẹ̀mí ẹni yìí lẹ́jọ́.
Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan Fọwọ́ sí I Pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lómìnira Láti Ṣe Ẹ̀sìn Wọn
Ní September 4, 2014, orílẹ̀-èdè Kyrgyzstan tẹ̀ lé àdéhùn tí wọ́n ṣe pẹ̀lú Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè láti má fi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn táwọn èèyàn ní dù wọ́n, ìyẹn jẹ́ kí wọ́n gba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyè láti ṣe ẹ̀sìn wọn jákèjádò orílẹ̀-èdè náà.