Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn ará ìlú lọ́kùnrin lóbìnrin tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà rèé níwájú Ilé Ẹjọ́ Tó Ń Kọ́kọ́ Gbọ́ Ẹjọ́ ní Ulaanbaatar tó jẹ́ olú-ìlú Mòǹgólíà.

AUGUST 24, 2018
MONGOLIA

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Lómìnira Ẹ̀sìn ní Mòǹgólíà: Ìjọba Pa Dà Forúkọ Ẹ̀sìn Wọn Sílẹ̀ Lábẹ́ Òfin

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Lómìnira Ẹ̀sìn ní Mòǹgólíà: Ìjọba Pa Dà Forúkọ Ẹ̀sìn Wọn Sílẹ̀ Lábẹ́ Òfin

Ní June 14, 2018, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Ulaanbaatar tó jẹ́ olú-ìlú orílẹ̀-èdè Mòǹgólíà, gba ìwé ẹ̀rí kan látọ̀dọ̀ Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ìlú, pé ìjọba ti pa dà forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin lórílẹ̀-èdè náà.

Ìwé ẹ̀rí tó jẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè máa ṣe ẹ̀sìn wọn ní Ulaanbaatar.

Ìjọba sọ fáwọn ẹlẹ́sìn pé ọdọọdún ni kí wọ́n máa forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ ní Mòǹgólíà, àtìgbà táwọn ará wa sì ti kọ́kọ́ forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin lọ́dún 1999 ni wọ́n ti ń ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ lọ́dún 2015, Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ìlú ò gbà káwọn ará wa forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ ní Ulaanbaatar. Nígbà tó di January 2017, Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ìlú sọ pe ìjọba fagi lé àǹfààní tí àwọn ará ní láti ṣe ẹ̀sìn wọn. Àwọn tó ṣojú fún Àjọ náà ò sọ ohunkóhun tó mú kí wọ́n ṣe ìpinnu yìí. Làwọn ará bá sọ pé àwọn máa gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sílé ẹjọ́.

Nígbà tí Ilé Ẹjọ́ ń gbọ́ ẹjọ́ náà, agbẹjọ́rò Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ìlú gbìyànjú láti fi ẹjọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà dá ṣe ẹ̀rí, ìyẹn bí wọ́n ṣe sọ pé kí ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé àwọn àjọ tá a fi forúkọ ẹ̀sìn wa sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní Rọ́ṣíà. Àmọ́ àwọn agbẹjọ́rò wa jẹ́ kó ṣe kedere pé ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ni ò fara mọ́ ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ dá ní Rọ́ṣíà àti pé ọ̀rọ̀ náà ti dé àwọn ilé ẹjọ́ àgbáyé. Wọ́n tún rán ilé ẹjọ́ létí pé ẹ̀yìn tí Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ìlú ṣèpinnu tiwọn ni ọ̀rọ̀ ti Rọ́ṣíà wáyé, torí náà, Àjọ náà ò lè sọ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Rọ́ṣíà ló mú káwọn ṣèpinnu táwọn ṣe.

Ilé Ẹjọ́ fagi lé ìpinnu tí Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ìlú ṣe, wọ́n ní àhesọ ọ̀rọ̀ lásán ni Àjọ náà gùn lé tí wọ́n fi ṣèpinnu, wọn ò sì rí ẹ̀rí kankan mú wá pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ohunkóhun tó léwu. Ilé Ẹjọ́ náà tún rí i pé Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ìlú fi ẹ̀tọ́ táwọn ará wa ní lábẹ́ òfin dù wọ́n, tó fi mọ́ òmìnira láti ṣe ẹ̀sìn wọn tàbí ohun tí wọ́n gbà gbọ́.

Jason Wise, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn agbẹjọ́rò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú ẹjọ́ yìí sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò di dandan kéèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ forúkọ ẹ̀sìn sílẹ̀ lábẹ́ òfin kó tó lè lo ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti òmìnira tí òfin sọ pé ó ní, síbẹ̀ kì í sábà rọrùn láti jọ́sìn fàlàlà láìkọ́kọ́ forúkọ sílẹ̀. Ara àwọn àǹfààní tá à ń rí bá a ṣe forúkọ ẹ̀sìn wa sílẹ̀ ni pé ó ń jẹ́ kó rọrùn fún wa láti kó Bíbélì àtàwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì wọ̀lú, ká lè ní ibi ìjọsìn, ká sì lè yá àwọn ibi tá a ti máa ṣe àpéjọ. Inú wa dùn pé Ilé Ẹjọ́ fagi lé ìpinnu tí Àjọ Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ìlú ṣe nílùú Ulaanbaatar, tí wọ́n sì gbà pé irú ìpinnu bẹ́ẹ̀ máa ṣàkóbá fún òmìnira tá a ní láti ṣe ẹ̀sìn wa àti òmìnira tá a ní láti pé jọ ní Mòǹgólíà.”