Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ilé arákùnrin wa kan tí omi wọ̀ ní ìlú Ashland, ìpínlẹ̀ Nebraska. Àwọn ará tó yọ̀ǹda ara wọn ti bẹ̀rẹ̀ sí í palẹ̀ ìdọ́tí ibẹ̀ mọ́.

APRIL 16, 2019
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Omíyalé Ba Nǹkan Jẹ́ Láàárín Agbègbè Ìwọ̀ Oòrùn Amẹ́ríkà

Omíyalé Ba Nǹkan Jẹ́ Láàárín Agbègbè Ìwọ̀ Oòrùn Amẹ́ríkà

Òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá àti yìnyín tó yọ́ fa omíyalé ní ìpínlẹ̀ Nebraska àti Iowa lóṣù March 2019. Omíyalé náà mú kí àwọn odò tó wà lágbègbè náà kún kọjá ààlà, àwọn ibi tó ń gba omi dúró ya lulẹ̀, ó ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé jẹ́, ó sì pa ó kéré tán èèyàn mẹ́rin.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Amẹ́ríkà sọ pé kò sí ìkankan lára ẹgbẹ̀rún márùn-ún àti mẹ́tàlélọ́gọ́fà (5,123) akéde tó wà níbẹ̀ tó kú tàbí tó fara pa. Àmọ́ akéde mẹ́rìnlélọ́gọ́rin (84) ní láti kúrò níbi tí wọ́n ń gbé. Yàtọ̀ síyẹn, ilé mẹ́jọ àwọn ará wa bà jẹ́ gan-an, ilé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (34) míì sì bà jẹ́ díẹ̀.

Àwọn ará ìjọ lágbègbè náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í yọ̀ǹda ara wọn láti palẹ̀ ìdọ̀tí mọ́, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ará tó wà ní Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ. Àwọn alábòójútó àyíká tó wà lágbègbè tí àjálù náà ti ṣẹlẹ̀ ń fáwọn ará tọ́rọ̀ kàn níṣìírí.

Àdúrà wa ni pé kí ìrànlọ́wọ́ táwọn ará wa rí gbà nípa tara àti nípa tẹ̀mí tù wọ́n nínú lásìkò ìṣòro yìí.​—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.