Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

OCTOBER 24, 2016
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Àwọn Ẹlẹ́rìí Ṣèrànwọ́ Gan-an Lẹ́yìn Tí Ìjì Líle Hurricane Matthew

Àwọn Ẹlẹ́rìí Ṣèrànwọ́ Gan-an Lẹ́yìn Tí Ìjì Líle Hurricane Matthew

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣèrànwọ́ fáwọn ará wọn àtàwọn míì tó ń gbé níbi tí ìjì líle kan tí wọ́n ń pè ní Hurricane Matthew ti ṣọṣẹ́. Níbẹ̀rẹ̀ oṣù October, ọdún 2016, ìjì yìí jà lórílẹ̀-èdè Bahamas, àgbègbè Caribbean àti gúúsù ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Nǹkan bí ìdajì nínú ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [1,400] àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Bahamas ni ìjì náà ṣàkóbá fún. Àwọn ará wọn kó oúnjẹ, omi àtàwọn nǹkan pàtàkì míì ránṣẹ́ sí ibi méjì lórílẹ̀-èdè náà kí wọ́n lè bójú tó àwọn tí àjálù dé bá.

Lórílẹ̀-èdè Cuba, ilé àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́rìnlélọ́gọ́fà [124] ló bà jẹ́, ilé mọ́kànlélọ́gbọ̀n [31] ló sì wó wómúwómú.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ọgọ́rùn-ún méje [700] ni ìjì náà lé kúrò nílé wọn lórílẹ̀-èdè Haiti. Mẹ́tàléláàádọ́rin [73] ni ilé àwọn Ẹlẹ́rìí tó bà jẹ́ pátápátá, ibi ìjọsìn wọn mẹ́rin ló sì pa rẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, ilé tó jẹ́ igba ó lé mẹ́rìnléláàádọ́rin [274] ló bà jẹ́, ibi ìjọsìn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] sì tún bà jẹ́. Àwọn ará wọn fi oúnjẹ àti oògùn ránṣẹ́ sí àwọn tí àjálù dé bá, wọ́n sì ra àgọ́ fún àwọn tí ò nílé mọ́ kí wọ́n lè máa gbébẹ̀ fúngbà díẹ̀.

Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ìjì yẹn ba ilé àwọn Ẹlẹ́rìí márùndínláàádóje [125] jẹ́. Ìròyìn tá a gbọ́ fi hàn pé ìṣòro tó le jù tí ìjì náà dá sílẹ̀ ni omíyalé tó ṣẹlẹ̀ torí àwọn odò tó kún àkúnya.

Láti oríléeṣẹ́ wa ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣètò bá a ṣe ń ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù dé bá, wọ́n ń lo owó táwọn èèyàn fi ń ṣètọrẹ fún iṣẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé. David A. Semonian tó jẹ́ agbẹnusọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan tó kú nínú àjálù tó ṣẹlẹ̀ yìí, àánú àwọn téèyàn wọn bá ìṣẹ̀lẹ̀ yìí lọ ṣe wá gan-an.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, 1-718-560-5000

Bahamas: Maxwell Dean, 1-242-422-6472

Haiti: Daniel Lainé, 509-2813-1560