DECEMBER 29, 2017
PHILIPPINES
Ìjì Méjì Ṣọṣẹ́ ní Philippines
Ìjì gbẹ̀mígbẹ̀mí méjì tí wọ́n ń pè ní Kai-tak (táwọn aráàlú mọ̀ sí Urduja) àti Tembin (táwọn aráàlú mọ̀ sí Vinta) jà lórílẹ̀-èdè Philippines, ó sì lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn kúrò nílé. Àwọn ìjì náà mú kí omi yalé, kí ẹrẹ̀ sì ya wọ̀lú lápá ìparí oṣù December.
Àwọn ìjì náà ba Gbọ̀ngàn Ìjọba méjì àti ilé mẹ́fà tó jẹ́ tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́, ó sì di dandan káwọn igba ó lé mọ́kàlélọ́gọ́rin (281) ìdílé kó kúrò nílé wọn. Ó dùn wá gan-an láti sọ pé nílùú Lanao del Norte, arábìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún (24) mumi yó, ó sì kú.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè náà ti dìde ìrànwọ́ fáwọn èèyàn. Àwọn aṣojú láti ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Philippines ti ń múra láti lọ ṣèbẹ̀wò sí ibi tí àjálù ti ṣẹlẹ̀ kí wọ́n lè mọ àwọn nǹkan míì táwọn ará tún máa nílò, kí wọ́n sì lè fi Bíbélì tù wọ́n nínú kínú wọn lè máa dùn.
A bá gbogbo àwọn tọ́rọ̀ kàn, tí àjálù sì ṣẹlẹ̀ sí kẹ́dùn. Bí iṣẹ́ ìrànwọ́ náà ṣe ń tẹ̀ síwájú, ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní yéé fi ẹ̀mí rẹ̀ àti ètò rẹ̀ tu àwọn èèyàn nínú, kó sì rà wọ́n lọ́wọ́.—Sáàmù 9:9; Aísáyà 51:12.
Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:
Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000
Philippines: Dean Jacek, +63-2-224-4444