DECEMBER 13, 2016
SOLOMON ISLANDS
Ìmìtìtì Ilẹ̀ Tó Wáyé ní Solomon Islands Mú Kí Ẹ̀rù Ba Àwọn Aráàlú Pé Ìjì Líle Lè Jà
Ní December 9, 2016, ìmìtìtì ilẹ̀ tó le gan-an wáyé níbi tí kò jìnnà sí etíkun ní erékùṣù Solomon Islands. Léraléra ni ilẹ̀ tún rọra mì tìtì lẹ́yìn ti àkọ́kọ́ yẹn, ìyẹn sì mú kí ìjì jà lórí òkun, àmọ́ ọwọ́ ìjì yẹn ò fi bẹ́ẹ̀ le. Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan ò kú ní àgbègbè náà, ìkankan nínú wọn ò fara pa, ìkankan nínú àwọn ohun ìní wọn ò sì bà jẹ́ kọjá àtúnṣe. Àmọ́ torí pé ìlú Honiara, tó jẹ́ olú-ìlú erékùṣù Solomon Islands, tó sì wà létíkun ni ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà, wọ́n kó àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì náà kúrò níbẹ̀ lọ sí àgbègbè kan tó wà lórí òkè, torí pé iléeṣẹ́ Pacific Tsunami Warning Center ti kìlọ̀ fáwọn èèyàn pé ìjì líle lè wáyé láwọn àgbègbè tó wà létíkun yẹn. Àmọ́ ní báyìí tí nǹkan ti rọlẹ̀, gbogbo wọn ti pa dà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì náà, wọ́n sì ti ń bá iṣẹ́ wọn lọ bíi ti tẹ́lẹ̀.
Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:
Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000
Solomon Islands: Lency Lamani, +677-22241