APRIL 25, 2019
SOUTH KOREA
Iná Ńlá Sọ Nínú Igbó Létí Ìlà Oòrùn South Korea
Ní April 4, 2019, iná ńlá kan sọ létí ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè South Korea ní agbègbè tí wọ́n ń pè ní Gangwon Province. Kò pẹ́ rárá tí iná náà fi ràn, èyí sì mú kí ìjọba kéde pé wàhálà ti wọ̀lú káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Kí wọ́n tó lè kápá iná náà, ó ti jó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) eékà ilẹ̀, ó sì ti pa èèyàn méjì.
Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ròyìn pé kò sí ìkankan lára àwọn ará wa tó kú. Àmọ́ iná náà jó ilé mẹ́jọ tí àwọn ará wa mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) ń gbé. Ẹ̀ka ọ́fíìsì dá Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù sílẹ̀, àwọn alábòójútó àyíká tó wà lágbègbè náà àtàwọn alàgbà ìjọ ń fáwọn tí àjàlù yìí kàn níṣìírí, wọ́n sì ń pèsè ohun tí wọ́n nílò fún wọn.
Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa jẹ́ ‘ibi ààbò àti okun pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àkókò wàhálà’ fáwọn ará wa yìí.—Sáàmù 46:1.