DECEMBER 20, 2016
SOUTH KOREA
Ilé Ẹjọ́ Ìjọba ti Ilẹ̀ South Korea Máa Tó Ṣe Ìpinnu Ńlá Kan
Ìpinnu mánigbàgbé kan ṣì wà tí Ilé Ẹjọ́ Ìjọba ti Ilẹ̀ South Korea máa tó ṣe, torí wọ́n tún ti ń gbé e yẹ̀ wò bóyá ó bófin mu kí wọ́n máa lo Òfin Iṣẹ́ Ológun láti fìyà jẹ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Àtìgbà tí Ilé Ẹjọ́ Ìjọba ti dá ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀ ní July 2015 ni ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń retí ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ náà máa ṣe. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, Han-chul Park tó jẹ́ ààrẹ Ilé Ẹjọ́ náà sọ pé kóun tó lo sáà òun tán ní January 30, 2017, Ilé Ẹjọ́ náà máa ṣèpinnu lórí ọ̀rọ̀ ọ̀hún.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Èèyàn Ló Máa Kàn
Ilé Ẹjọ́ Ìjọba ni ilé ẹjọ́ tó ga jù lọ ní South Korea, àwọn ló máa ń pinnu bóyá òfin kan bá òfin orílẹ̀-èdè náà mu àbí ó ta kò ó. Ìjọba ti ní kí Ilé Ẹjọ́ náà tún Òfin Iṣẹ́ Ológun gbé yẹ̀ wò, pàápàá níbi tó ti sọ pé kí wọ́n máa rán àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò bá jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun lọ sẹ́wọ̀n. Wọ́n ní kí Ilé Ẹjọ́ náà pinnu bóyá ìyà tí wọ́n fi ń jẹ àwọn èèyàn yìí ta ko Òfin Ilẹ̀ South Korea, bóyá ó sì ta ko ẹ̀tọ́ táwọn èèyàn ní lábẹ́ òfin láti lómìnira ẹ̀rí ọkàn àti ẹ̀sìn.
Tí Ilé Ẹjọ́ náà bá sọ pé bí ìjọba ṣe ń fi àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun sẹ́wọ̀n láti àìmọye ọdún ò bófin mu, ó máa di dandan kí ìjọba South Korea wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ náà. Ó ṣeé ṣe kí ìyẹn mú kí ìjọba ṣíwọ́ bí wọ́n ṣe ń fẹ̀sùn kan àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun, kí ilé ẹjọ́ máa dá wọn láre, kí wọ́n má sì rán wọn lọ sẹ́wọ̀n mọ́.
Ẹnu Àwọn Ilé Ẹjọ́ Ò Kò
Ilé Ẹjọ́ Ìjọba ti gbé ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò rí lọ́dún 2004 àti 2011. Ẹ̀ẹ̀mejì yẹn ni wọ́n ti sọ pé ó bófin mu kí wọ́n máa fìyà jẹ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Bákan náà, lọ́dún 2004 àti 2007, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè South Korea, tó jẹ́ ilé ẹjọ́ tó ga jù tó ń gbọ́ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́run, tó sì máa ń gbọ́ ẹjọ́ gbẹ̀yìn, sọ pé èèyàn ò lè sọ pé òun ò ṣiṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kó ṣe é. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ilé ẹjọ́ tó ga yìí ti fẹnu sí ọ̀rọ̀ yìí, ọ̀rọ̀ náà ò tíì lójú, kódà, àwọn ilé ẹjọ́ kan ṣì ń níṣòro lórí ẹ̀.
Gbogbo ìpele ilé ẹjọ́ ní South Korea ló sọ pé ó nira fáwọn láti rán àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun lọ sẹ́wọ̀n. Látìgbà tí Ilé Ẹjọ́ Ìjọba ti ṣèpinnu lórí ọ̀rọ̀ yìí lọ́dún 2011, Ilé Ẹjọ́ náà fúnra wọn ti fọwọ́ sí i pé àwọn máa gbọ́ ẹjọ́ tí àwọn ilé ẹjọ́ ìlú méje gbé wá àtàwọn ẹjọ́ méjìlélógún [22] míì táwọn èèyàn gbé wá. Kì í tún ṣe gbogbo ẹjọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ dá làwọn èèyàn ń fara mọ́, torí náà, ogójì [40] ẹjọ́ ló ṣì wà lọ́rùn Ilé Ẹjọ́ Ìjọba lórí ọ̀rọ̀ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Láti May 2015, àwọn mẹ́sàn-án tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun ni ilé ẹjọ́ ti dá láre.
Ní October 2016, ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn kan kíyè sí i bí ẹnu àwọn ilé ẹjọ́ ìlú àtàwọn ilé ẹjọ́ gíga ò ṣe kò lórí ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n wá sọ pé: “Kò tíì ṣẹlẹ̀ rí, pé kí ẹnu má kò lórí ofin kan ṣoṣo, kí kálukú wá máa yí i síbí, yí i sọ́hùn-ún.” Fúngbà àkọ́kọ́, ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn yìí kan náà dá àwọn mẹ́ta tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun láre. Inú ẹgbẹ́ Seoul Bar Association dùn sí ìpinnu tí ilé ẹjọ́ ṣe yẹn, wọ́n ní “mánigbàgbé” ló jẹ́. Han-kyu Kim, tó jẹ́ ààrẹ ẹgbẹ́ Seoul Bar Association, sọ pé ọwọ́ Ilé Ẹjọ́ Ìjọba lọ̀rọ̀ náà kù sí báyìí.
“Kò tíì ṣẹlẹ̀ rí, pé kí ẹnu má kò lórí ofin kan ṣoṣo, kí kálukú wá máa yí i síbí, yí i sọ́hùn-ún.”—Ilé Ẹjọ́ Gwangju, Third Criminal Division, nígbà tí wọ́n ń dá ẹjọ́ Lak-hoon Cho, ní October 18, 2016
Ọ̀rọ̀ Tó Ti Pẹ́ Nílẹ̀ Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Lójú
Ọ̀gbẹ́nì Kim tún sọ pé: “Ara àwọn aráàlú ti wà lọ́nà láti gbọ́ ohun tí [Ilé Ẹjọ́ Ìjọba] máa sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n retí pé ilé ẹjọ́ yìí máa gbèjà àwọn. Àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun ṣì ń jìyà torí ẹ̀sùn ọ̀daràn tó ti wà lọ́rùn wọn, ìjọba ò sì tún fìgbà kan rò ó pé kí wọ́n jẹ́ káwọn ọkùnrin yìí ṣiṣẹ́ àṣesìnlú dípò iṣẹ́ ológun. Mo rọ Ilé Ẹjọ́ Ìjọba pé kí wọ́n tètè ṣèpinnu lórí ọ̀rọ̀ yìí, torí àwọn nìkan ló kù tó lè jà fẹ́tọ̀ọ́ àwọn aráàlú.”
Láti ọgọ́ta [60] ọdún báyìí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìdílé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè South Korea lọ̀rọ̀ yìí ti kàn. Bàbá àwọn kan, àwọn ọmọ wọn lọ́kùnrin, àwọn ẹ̀gbọ́n àtàwọn àbúrò wọn ló ti ṣẹ̀wọ̀n torí wọ́n kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun. Tí Ilé Ẹjọ́ Ìjọba bá ṣèpinnu tó gbe àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun yìí, wọn ò ní ṣẹ̀wọ̀n mọ́ torí ẹ̀wọ̀n tí wọ́n ń rán wọn lọ ò ṣàǹfààní kankan, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́kùnrin ló sì máa bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi ń kàn wọ́n, tó sì ń pa wọ́n lára. Àti pé kò ní sẹ́ni tó máa fi ẹ̀tọ́ òmìnira ẹ̀rí ọkàn àti òmìnira ẹ̀sìn du gbogbo aráàlú mọ́.
Ojú Ilé Ẹjọ́ Ìjọba ni gbogbo èèyàn ń wò báyìí, wọ́n ń retí ìpinnu gbankọgbì tí wọ́n máa tó ṣe.