OCTOBER 19, 2016
SOUTH KOREA
Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ní South Korea Dá Àwọn tí Ẹ̀rí Ọkàn Ò Jẹ́ Kí Wọ́n Ṣiṣẹ́ Ológun Láre
Ní October 18, 2016, ẹ̀ka tó ń gbọ́ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ní Ilé Ẹjọ́ Gwangju sọ pé Ọ̀gbẹ́ni Hye-min Kim, Lak-hoon Cho àti Hyeong-geun Kim kò jẹ̀bi bí wọ́n ṣe sọ pé àwọn ò ṣiṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣe é. Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí, àwọn sì ni ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn máa kọ́kọ́ dá láre lórí ọ̀rọ̀ yìí lórílẹ̀-èdè South Korea.
Adájọ́ Young-shik Kim ṣàlàyé pé: “Ilé Ẹjọ́ gbà pé torí wọn ò fẹ́ ṣe ohun tó ta ko ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn wọn àti ẹ̀rí ọkàn wọn ni wọ́n ṣe kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun. Èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin láti ṣe ẹ̀sìn tó wù ú, kó sì ṣe ohun tó bá bá ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ mu. Kò yẹ kí wọ́n fìyà jẹ̀ẹ̀yàn lórí ìyẹn.”
Tí àwọn tó pe àwọn ọ̀dọ́kùnrin yìí lẹ́jọ́ bá pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ọ̀rọ̀ yìí, a jẹ́ pé ẹjọ́ yìí máa dé iwájú Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ nìyẹn. Ẹjọ́ tó ti wà níwájú Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ báyìí lé ní ogójì [40], lórí ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin tí wọ́n dá lẹ́bi torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Ọ̀gbẹ́ni Philip Brumley, tó jẹ́ Agbẹjọ́rò Àgbà fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ àti Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin lórílẹ̀-èdè South Korea ò fọwọ́ sí i títí di báyìí pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ àtikọ iṣẹ́ ológun tí ẹ̀rí ọkàn ò bá jẹ́ kó ṣe é, ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ti ṣe ohun tí ìjọba àpapọ̀ ní kí àwọn orílẹ̀-èdè ṣe kárí ayé, pé kí wọ́n fọwọ́ sí i pé èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ìpinnu tó lé ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500] ni Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè ti ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí, láti fi hàn pé wọ́n fọwọ́ sí i.”