JULY 19, 2019
SPAIN
Ìṣẹ̀lẹ̀ Mánigbàgbé: Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Tá A Tún Ṣe Jáde Lédè Sípáníìṣì
Ní Friday, July 19, 2019, lọ́jọ́ àkọ́kọ́ Àpéjọ Àgbáyé tá a pe àkọlé rẹ̀ ní, “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! tá a ṣe ní Madrid, lórílẹ̀-èdè Spain, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe jáde lédè Sípáníìṣì. Ọjọ́ pẹ́ tá a ti ń retí ẹ̀! Bíbélì tá a tún ṣe yìí ti wà lórí ìkànnì jw.org®, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa kárí ayé tó lé ní mílíọ̀nù méjì àtààbọ̀ tó ń sọ èdè Spanish lè kà á níbẹ̀ tàbí wà á jáde. Àwọn tó ń sọ èdè yìí ló pọ̀ jù lọ nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. *
Arákùnrin Gerrit Lösch, tó jẹ́ ọkàn lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí mú Bíbélì yìí jáde nínú fídíò tí a ti gbà ohùn àti àwòrán rẹ̀ sílẹ̀ ní àpéjọ àgbáyé tó wáyé ní pápá Ìṣeré Wanda Metropolitano nílùú Madrid. A ṣe àtagbà fídíò yìí sí ibi mọ́kànlá (11) míì ní orílẹ̀-èdè Spain. Kété lẹ́yìn náà, a gbé fídíò náà sórí ètò JW Broadcasting®.
Níbi àpéjọ náà, a ṣe àkànṣe ètò tó máa jẹ́ kí àwọn tó wà níbẹ̀ lè wa Bíbélì yìí jáde ní ẹ̀dà EPUB, JWPUB tàbí PDF lórí ìkànnì jw.org. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà láwọn ibi mọ́kànlá yòókù ní orílẹ̀-èdè Spain níbi tá a ṣe àtagbà ètò yìí sí ní àǹfààní láti wa ẹ̀dà Bíbélì yìí sórí fóònú tàbí ẹ̀rọ alágbèéká wọn nípa lílo ètò ìṣiṣẹ́ íńtánẹ́ẹ̀tì JW Box tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dìídì ṣe. Ó lé ní ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún méjì (1,200) àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn tó ti wà ní sẹpẹ́ níbi àpéjọ àgbáyé yìí àti láwọn ibòmíì tá a ṣètò láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tó wá kí wọ́n lè wa Bíbélì sórí fóònù wọn.
Ìpèníjà ńlá ni iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì ní èdè Sípáníìṣì jẹ́, torí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń sọ èdè Sípáníìṣì kárí ayé yàtọ̀ síra. Arákùnrin Pedro Gil, ọkàn lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ní orílẹ̀-èdè Spain sọ pé: “Kárí ayé, nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (577) mílíọ̀nù èèyàn ló ń sọ èdè Spanish, àmọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àtàwọn àgbékalẹ̀ wọn ní ìtumọ̀ tó yàtọ̀ síra láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn. Yàtọ̀ sí ìyẹn, èdè Sípáníìṣì tí à ń sọ báyìí ti yàtọ̀ pátápátá sí bí àwọn èèyàn ṣe ń sọ ọ́ lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn.”
Ká lè ran àwọn atúmọ̀ èdè lọ́wọ́ láti ṣe ìtumọ̀ tó péye tó sì rọrùn láti kà, a kàn sí nǹkan bí ọgọ́rùn-ún kan (100) àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà ní orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti ràn wá lọ́wọ́. Gbogbo ẹ̀ gba nǹkan bí ọdún mẹ́rin àtààbọ̀ kó tó parí.
Arákùnrin Gil sọ pé: “Èdè tó bágbà mu tá a lò nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe lédè Sípáníìṣì yìí máa tètè yé àwọn tó bá kà á. Nípa bẹ́ẹ̀, á rọrùn fún àwọn akéde láti lò lóde ẹ̀rí àti ní ìpàdé. Inú wa dùn pé àtúnṣe yìí á jẹ́ kí àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin tó ń sọ èdè Sípáníìṣì sún mọ́ Jèhófà sí i.”
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìtumọ̀ tuntun tó ń mú ìyìn bá orúkọ rẹ̀. A nígbàgbọ́ pé Bíbélì tá a tún ṣe yìí máa ran àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ láti máa bá a lọ láti wàásù “dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.”—Ìṣe 1:8.
^ ìpínrọ̀ 2 Iye Bíbélì tá a fẹ́ tẹ̀ jáde lédè yìí pọ̀ gan-an, torí náà, a ò pín ẹ̀dà Bíbélì tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ mú jáde ní àpéjọ yìí. Àmọ́, àwọn ìjọ tó ń sọ èdè Sípáníìṣì máa rí ẹ̀dà Bíbélì yìí gbà ní kété tó bá ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó. A máa gbé e sí orí JW Library® lẹ́yìn ọjọ́ Monday, July 22.