FEBRUARY 24, 2020
OHUN TUNTUN
Abala Tuntun—Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
Abala tuntun kan ti wà lórí ìkànnì jw.org báyìí tá a ń pè ní “Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì.”
Àìmọye èèyàn ló máa ń lọ sórí ìkànnì lóṣooṣù láti wá ìtumọ̀ àwọn ẹsẹ Bíbélì kan. Abala tá a pè ní “Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì” ṣàlàyé ìtumọ̀ irú àwọn ẹsẹ Bíbélì bẹ́ẹ̀, ó sì tún sọ àwọn àlàyé tó yí àwọn ẹsẹ náà ká.
Kó o lè rí àwọn àlàyé yìí, lọ sí abala “Ẹ̀kọ́ Bíbélì,” lẹ́yìn náà tẹ “Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì.”